ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 45:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ títí láé àti láéláé;+

      Ọ̀pá àṣẹ ìjọba rẹ jẹ́ ọ̀pá àṣẹ ìdúróṣinṣin.*+

  • Sáàmù 72:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 72 Ọlọ́run, sọ àwọn ìdájọ́ rẹ fún ọba,

      Kí o sì kọ́ ọmọ ọba ní òdodo rẹ.+

  • Àìsáyà 9:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Àkóso* rẹ̀ á máa gbilẹ̀ títí lọ,

      Àlàáfíà kò sì ní lópin,+

      Lórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti lórí ìjọba rẹ̀,

      Kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+ kó sì gbé e ró,

      Nípasẹ̀ ìdájọ́+ tí ó tọ́ àti òdodo,+

      Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

      Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.

  • Àìsáyà 11:4, 5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*

      Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé.

      Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+

      Ó sì máa fi èémí* ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+

       5 Òdodo ló máa jẹ́ àmùrè ìgbáròkó rẹ̀,

      Òtítọ́ ló sì máa jẹ́ àmùrè ìbàdí rẹ̀.+

  • Jeremáyà 23:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá gbé èéhù* kan tó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Ọba kan máa jẹ,+ á sì fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, á dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, á sì ṣe òdodo ní ilẹ̀ náà.+

  • Sekaráyà 9:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.

      Kígbe ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù.

      Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.+

      Olódodo ni, ó sì ń mú ìgbàlà bọ̀,*

      Ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀,+ ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

      Àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+

  • Hébérù 1:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+

  • Ìfihàn 19:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Mo rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, wò ó! ẹṣin funfun kan.+ A pe ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ ní Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé+ àti Olóòótọ́,+ ó ń ṣèdájọ́, ó sì ń fi òdodo+ jagun lọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́