-
Àìsáyà 20:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Jèhófà wá sọ pé: “Bí ìránṣẹ́ mi Àìsáyà ṣe rìn káàkiri ní ìhòòhò, láìwọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, láti fi ṣe àmì+ àti àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì+ àti Etiópíà,+ 4 bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọba Ásíríà máa kó àwọn ẹrú Íjíbítì+ àti Etiópíà lọ sí ìgbèkùn, àwọn ọmọdékùnrin àtàwọn àgbà ọkùnrin, ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà, ìdí wọn á sì hàn síta, Íjíbítì máa rin ìhòòhò.*
-
-
Jeremáyà 46:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ pé: ‘Wò ó, màá yíjú sí Ámọ́nì+ láti Nóò*+ àti sí Fáráò àti Íjíbítì àti àwọn ọlọ́run rẹ̀+ àti àwọn ọba rẹ̀, àní màá yíjú sí Fáráò àti gbogbo àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.’+
26 “‘Màá fà wọ́n lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* wọn, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì+ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á máa gbé inú rẹ̀ bíi ti àtijọ́,’ ni Jèhófà wí.+
-