12 Màá sọ iná sí ilé àwọn ọlọ́run Íjíbítì, ọba náà á sun wọ́n,+ á sì kó wọn lọ sí oko ẹrú. Á da ilẹ̀ Íjíbítì bora bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń da ẹ̀wù bo ara rẹ̀, á sì jáde kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà. 13 Á fọ́ àwọn òpó Bẹti-ṣémẹ́ṣì tó wà nílẹ̀ Íjíbítì sí wẹ́wẹ́, á sì dáná sun ilé àwọn ọlọ́run Íjíbítì.”’”