ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 11:6, 7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ìkookò máa bá ọ̀dọ́ àgùntàn gbé fúngbà díẹ̀,+

      Àmọ̀tẹ́kùn máa dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́,

      Ọmọ màlúù, kìnnìún* àti ẹran tó sanra á jọ wà pa pọ̀;*+

      Ọmọ kékeré á sì máa dà wọ́n.

       7 Màlúù àti bíárì á jọ máa jẹun,

      Àwọn ọmọ wọn á sì jọ dùbúlẹ̀.

      Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù.+

  • Àìsáyà 65:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn máa jẹun pa pọ̀,

      Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù,+

      Erùpẹ̀ sì ni ejò á máa jẹ.

      Wọn ò ní ṣe ìpalára kankan, wọn ò sì ní fa ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi,”+ ni Jèhófà wí.

  • Ìsíkíẹ́lì 34:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 “‘“Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà,+ èmi yóò sì pa àwọn ẹranko ẹhànnà run ní ilẹ̀ náà,+ kí wọ́n lè máa gbé láìséwu nínú aginjù, kí wọ́n sì sùn nínú igbó.+

  • Hósíà 2:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ní ọjọ́ yẹn, màá bá àwọn ẹran inú igbó dá májẹ̀mú nítorí wọn,+

      Màá sì bá àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ohun tó ń rákò lórí ilẹ̀ dá májẹ̀mú;+

      Màá mú ọfà* àti idà àti ogun kúrò ní ilẹ̀ náà,+

      Màá sì jẹ́ kí wọ́n dùbúlẹ̀* ní ààbò.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́