ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 45:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 45 Ohun tí Jèhófà sọ fún ẹni tó yàn nìyí, fún Kírúsì,+

      Ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú,+

      Láti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba níwájú rẹ̀,+

      Láti gba ohun ìjà* àwọn ọba,

      Láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì níwájú rẹ̀,

      Kí wọ́n má sì ti àwọn ẹnubodè:

  • Jeremáyà 51:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 “Ẹ dán ọfà;+ ẹ gbé àwọn apata ribiti.*

      Jèhófà ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Mídíà sókè,+

      Torí ó ní in lọ́kàn láti pa Bábílónì run.

      Nítorí ẹ̀san Jèhófà nìyí, ẹ̀san nítorí tẹ́ńpìlì rẹ̀.

  • Jeremáyà 51:27, 28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 “Ẹ gbé àmì kan sókè* ní ilẹ̀ náà.+

      Ẹ fun ìwo láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.

      Ẹ yan àwọn orílẹ̀-èdè* lé e lórí.

      Ẹ pe àwọn ìjọba Árárátì,+ Mínì àti Áṣíkénásì+ láti wá gbéjà kò ó.

      Ẹ yan agbanisíṣẹ́ ogun láti wá gbéjà kò ó.

      Ẹ jẹ́ kí àwọn ẹṣin gòkè wá bí eéṣú onírun gàn-ùn gàn-ùn.

      28 Ẹ yan àwọn orílẹ̀-èdè* lé e lórí,

      Àwọn ọba Mídíà,+ àwọn gómìnà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀

      Àti gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́