-
Jeremáyà 10:12-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Òun ni Aṣẹ̀dá ayé tó fi agbára rẹ̀ dá a,
Ẹni tó fi ọgbọ́n rẹ̀ dá ilẹ̀ tó ń mú èso jáde+
Tó sì fi òye rẹ̀ na ọ̀run bí aṣọ.+
14 Kálukú ń hùwà láìronú, wọn ò sì ní ìmọ̀.
15 Ẹ̀tàn* ni wọ́n, iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni wọ́n.+
Nígbà tí ọjọ́ ìbẹ̀wò wọn bá dé, wọ́n á ṣègbé.
16 Ọlọ́run* Jékọ́bù kò dà bí àwọn nǹkan yìí,
Nítorí òun ni Ẹni tó dá ohun gbogbo,
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+
-