ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 15:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Ábúrámù dá májẹ̀mú+ kan pé: “Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,+ láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, ìyẹn odò Yúfírétì:+

  • Ẹ́kísódù 3:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+

  • Léfítíkù 20:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún yín pé: “Ẹ ó gba ilẹ̀ wọn, màá sì fún yín kó lè di tiyín, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹni tó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn yòókù.”+

  • Diutarónómì 6:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Kí o fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì rí i pé ò ń pa wọ́n mọ́, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o sì lè pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́