-
Jeremáyà 3:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Nígbà tí mo rí ìyẹn, mo lé Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ lọ, mo sì já ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀+ fún un nítorí àgbèrè rẹ̀.+ Síbẹ̀, ẹ̀rù kò ba Júdà arábìnrin rẹ̀ tó ń ṣe békebèke; ṣe ni òun náà tún lọ ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ 9 Kò ka iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe sí àìdáa, ó ń sọ ilẹ̀ náà di ẹlẹ́gbin, ó sì ń bá àwọn òkúta àti igi ṣe àgbèrè.+
-
-
Jeremáyà 5:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Báwo ni mo ṣe lè dárí ohun tí o ṣe yìí jì ọ́?
Àwọn ọmọ rẹ ti fi mí sílẹ̀,
Wọ́n sì ń fi ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.+
Gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ ni mo fún wọn,
Ṣùgbọ́n wọn ò jáwọ́ nínú àgbèrè,
Wọ́n sì ń rọ́ lọ sí ilé aṣẹ́wó.
-