3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí.
3 “Ìgbà náà ni màá kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àgùntàn mi jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo fọ́n wọn ká sí,+ màá sì mú wọn pa dà wá sí ibi ìjẹko wọn,+ wọ́n á máa bímọ, wọ́n á sì di púpọ̀.+
13 Èmi yóò mú wọn jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì kó wọn jọ láti àwọn ilẹ̀. Èmi yóò mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn, màá sì bọ́ wọn lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó ń ṣàn àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ náà.
11 A ó sì mú kí àwọn èèyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì ṣọ̀kan,+ wọ́n á yan olórí fún ara wọn, wọ́n á sì jáde kúrò ní ilẹ̀ náà, nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ náà máa jẹ́ ní Jésírẹ́lì.+