-
Nọ́ńbà 18:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 “Sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé, ‘Ẹ ó máa gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí mo fún yín láti ọwọ́ wọn kó lè jẹ́ ogún+ yín, kí ẹ sì fi ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá náà ṣe ọrẹ fún Jèhófà.+ 27 Ìyẹn ló máa jẹ́ ọrẹ yín, bí ọkà láti ibi ìpakà+ tàbí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tó jáde láti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì tàbí òróró.
-
-
Diutarónómì 18:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Kí o fún un ní àkọ́so ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ àti irun tí o bá kọ́kọ́ rẹ́ lára agbo ẹran rẹ.+
-