-
Ẹ́sítà 8:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní báyìí, ẹ kọ ohunkóhun tó bá dáa lójú yín lórúkọ ọba nítorí àwọn Júù, kí ẹ sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé e, nítorí ìwé àṣẹ tí wọ́n bá kọ lórúkọ ọba, tí wọ́n sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé kò ṣeé yí pa dà.”+
-
-
Dáníẹ́lì 6:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba, àwọn aṣíwájú, àwọn baálẹ̀, àwọn olóyè jàǹkàn-jàǹkàn àti àwọn gómìnà ti gbìmọ̀ pọ̀ láti fi àṣẹ kan lélẹ̀ látọ̀dọ̀ ọba, kí wọ́n sì kà á léèwọ̀* pé, láàárín ọgbọ̀n (30) ọjọ́, ẹnikẹ́ni tó bá béèrè nǹkan lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí èèyàn èyíkéyìí yàtọ̀ sí ìwọ ọba, ká ju onítọ̀hún sínú ihò kìnnìún.+ 8 Ní báyìí, ọba, gbé àṣẹ náà kalẹ̀, kí o sì fọwọ́ sí i,+ kó má ṣeé yí pa dà, gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti Páṣíà, tí kò ṣeé fagi lé.”+
-