-
Dáníẹ́lì 8:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 “Ní apá ìparí ìjọba wọn, bí ìṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ṣe ń parí,* ọba kan tí ojú rẹ̀ le, tó lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ púpọ̀,* máa dìde. 24 Ó máa lágbára gan-an, àmọ́ kì í ṣe nípa agbára òun fúnra rẹ̀. Ó máa mú ìparun wá lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀,* ó máa ṣàṣeyọrí, ó sì máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́. Ó máa pa àwọn alágbára run àti àwọn tó jẹ́ ẹni mímọ́.+
-
-
Dáníẹ́lì 12:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nígbà náà, mo gbọ́ tí ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, tó wà lórí omi tó ń ṣàn sọ̀rọ̀, bó ṣe gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀ sókè ọ̀run, tó sì fi Ẹni tó wà láàyè títí láé búra pé:+ “Ó máa jẹ́ fún àkókò tí a yàn, àwọn àkókò tí a yàn àti ààbọ̀ àkókò.* Gbàrà tí fífọ́ agbára àwọn èèyàn mímọ́ túútúú bá ti dópin,+ gbogbo nǹkan yìí máa dópin.”
-