16 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! O ò ní pẹ́ kú,* àwọn èèyàn yìí á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọlọ́run àjèjì tó yí wọn ká ní ilẹ̀ tí wọ́n ń lọ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+ Wọ́n á pa mí tì,+ wọ́n á sì da májẹ̀mú mi tí mo bá wọn dá.+
3Ìgbà náà ni Jèhófà sọ fún mi pé: “Lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ tí ọkùnrin míì ti fẹ́, tó sì ń ṣe àgbèrè,+ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì+ bí wọ́n tilẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run míì,+ tí wọ́n sì fẹ́ràn ìṣù àjàrà gbígbẹ.”*