3 Lẹ́yìn náà, Mósè wá, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà àti gbogbo ìdájọ́ náà+ fún àwọn èèyàn, gbogbo àwọn èèyàn náà sì fohùn ṣọ̀kan, wọ́n fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe.”+
8 Ojúkojú* ni mò ń bá a sọ̀rọ̀,+ láì fọ̀rọ̀ pa mọ́, kì í ṣe lówelówe; ìrísí Jèhófà ló sì ń rí. Kí wá nìdí tí ẹ̀rù ò fi bà yín láti sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”
25 láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì títí di òní.+ Torí náà, mò ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mò ń rán wọn lójoojúmọ́, mo sì ń rán wọn léraléra.*+