ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Ọbadáyà 1-21
  • Ọbadáyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọbadáyà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ọbadáyà

ỌBADÁYÀ

1 Ìran tí Ọbadáyà* rí:

Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nípa Édómù nìyí:+

“A ti gbọ́ ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà,

Aṣojú kan ti lọ jíṣẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé:

‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká múra láti bá a jagun.’”+

 2 “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;

O ti tẹ́ pátápátá.+

 3 Ìgbéraga* ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,+

Ìwọ tó ń gbé ihò inú àpáta,

Ìwọ tó ń gbé ibi gíga, tí o sì ń sọ nínú ọkàn rẹ pé,

‘Ta ló lè rẹ̀ mí wálẹ̀?’

 4 Bí o bá tiẹ̀ kọ́lé sí ibi gíga* bí ẹyẹ idì,

Tàbí tí o kọ́ ìtẹ́ rẹ sáàárín àwọn ìràwọ̀,

Màá rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ láti ibẹ̀,” ni Jèhófà wí.

 5 “Bí àwọn olè bá wá bá ọ, àwọn ọlọ́ṣà ní òru,

(Ṣe ni wọ́n á run ọ́!)*

Ṣebí ohun tí wọ́n bá fẹ́ nìkan ni wọ́n á kó?

Tó bá sì jẹ́ àwọn tó ń kó èso àjàrà jọ ló wá bá ọ,

Ṣé wọn ò ní ṣẹ́ díẹ̀ kù fáwọn tó ń pèéṣẹ́?*+

 6 Ẹ wo bí wọ́n ṣe wá Ísọ̀ kàn!

Gbogbo ìṣúra tó fi pa mọ́ ni wọ́n ti wá jáde!

 7 Wọ́n ti lé ọ títí dé ẹnubodè.

Gbogbo àwọn tó bá ọ ṣàdéhùn* ti tàn ọ́ jẹ.

Àwọn tí ẹ jọ wà ní àlàáfíà ti borí rẹ.

Àwọn tí ẹ jọ ń jẹun* yóò dẹ àwọ̀n dè ọ́,

Àmọ́ ìwọ kò ní mọ̀.

 8 Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà wí,

“Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n run kúrò ní Édómù+

Èmi yóò sì pa òye run ní agbègbè olókè Ísọ̀.

 9 Ẹ̀rù yóò ba àwọn jagunjagun rẹ,+ ìwọ Témánì,+

Torí gbogbo ẹni tó wà ní agbègbè olókè Ísọ̀ ni yóò ṣègbé nítorí ìpakúpa.+

10 Nítorí ìwà ìkà tí o hù sí Jékọ́bù ọmọ ìyá rẹ,+

Ojú yóò tì ọ́,+

Ìwọ yóò sì ṣègbé títí láé.+

11 Ní ọjọ́ tí ìwọ ta kété sí ẹ̀gbẹ́ kan,

Ní ọjọ́ tí àwọn àjèjì mú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́rú,+

Nígbà tí àwọn àjèjì gba ẹnubodè rẹ̀ wọlé, tí wọ́n sì ṣẹ́ kèké+ lórí Jerúsálẹ́mù,

Ìwọ náà ṣe bíi tiwọn.

12 Kò yẹ kí o fi ọmọ ìyá rẹ ṣe yẹ̀yẹ́ ní ọjọ́ tí àjálù bá a,+

Kò yẹ kí o yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà ní ọjọ́ tí wọ́n ń ṣègbé lọ,+

Kò sì yẹ kí o máa fọ́nnu ní ọjọ́ wàhálà wọn.

13 Kò yẹ kí o wọ ìlú* àwọn èèyàn mi ní ọjọ́ àjálù wọn,+

Kò yẹ kí o fi í ṣe yẹ̀yẹ́ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀,

Kò sì yẹ kí o fọwọ́ kan ohun ìní rẹ̀ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀.+

14 Kò yẹ kí o dúró sí oríta láti pa àwọn èèyàn rẹ̀ tó ń sá lọ,+

Kò sì yẹ kí o fi àwọn èèyàn rẹ̀ tó yè bọ́ ní ọjọ́ wàhálà lé ọ̀tá lọ́wọ́.+

15 Nítorí ọjọ́ tí Jèhófà fẹ́ bá gbogbo orílẹ̀-èdè jà ti sún mọ́lé.+

Ohun tí o ṣe ni wọn yóò ṣe sí ọ.+

Ìwà tí o hù sí àwọn èèyàn ni wọn yóò hù sí ọ.

16 Bí o ṣe mu wáìnì lórí òkè mímọ́ mi,

Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa mu ìbínú mi nígbà gbogbo.+

Wọn yóò rọ́ ọ sí ọ̀fun, wọn yóò sì gbé e mì,

Yóò sì dà bíi pé wọn kò gbé ayé rí.

17 Àmọ́ àwọn tó sá àsálà yóò wà lórí Òkè Síónì,+

Yóò sì di mímọ́;+

Ilé Jékọ́bù yóò sì gba àwọn nǹkan tó jẹ́ tiwọn.+

18 Ilé Jékọ́bù yóò di iná,

Ilé Jósẹ́fù yóò di ọwọ́ iná,

Ilé Ísọ̀ yóò sì dà bí àgékù pòròpórò;

Wọn yóò ti iná bọ̀ wọ́n, wọn yóò sì run wọ́n,

Ẹnikẹ́ni kì yóò sì là á já ní ilé Ísọ̀,+

Torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.

19 Wọn yóò gba Négébù àti agbègbè olókè Ísọ̀,+

Agbègbè Ṣẹ́fẹ́là àti ilẹ̀ àwọn Filísínì.+

Wọn yóò gba ilẹ̀ Éfúrémù àti ilẹ̀ Samáríà,+

Bẹ́ńjámínì yóò sì gba Gílíádì.

20 Àwọn tó lọ sí ìgbèkùn látinú odi* yìí,+

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ni yóò gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì títí dé Sáréfátì.+

Àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù tó lọ sí ìgbèkùn ní Séfárádì ni yóò gba àwọn ìlú tó wà ní Négébù.+

21 Àwọn olùgbàlà yóò sì lọ sórí Òkè Síónì

Láti dá agbègbè olókè Ísọ̀ lẹ́jọ́,+

Ipò ọba yóò sì di ti Jèhófà.”+

Ó túmọ̀ sí “Ìránṣẹ́ Jèhófà.”

Tàbí “ìkọjá àyè.”

Tàbí kó jẹ́, “tiẹ̀ fò lọ sókè réré.”

Tàbí kó jẹ́, “Ohun mélòó ni wọ́n máa run?”

Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.

Tàbí “dá májẹ̀mú.”

Ní Héb., “jẹ búrẹ́dì.”

Ní Héb., “ẹnubodè.”

Tàbí “ògiri ààbò.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́