ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 27:41, 42
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 41 Ṣùgbọ́n Ísọ̀ di Jékọ́bù sínú torí pé bàbá rẹ̀ ti súre fún un,+ Ísọ̀ sì ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Ọjọ́ tí a máa ṣọ̀fọ̀ bàbá mi ti ń sún mọ́lé.+ Lẹ́yìn náà, ṣe ni màá pa Jékọ́bù àbúrò mi.” 42 Nígbà tí wọ́n sọ fún Rèbékà ohun tí Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà sọ, ojú ẹsẹ̀ ló ránṣẹ́ pe Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ àbúrò, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó! Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ ń wá bó ṣe máa pa ọ́ kó lè gbẹ̀san.*

  • Nọ́ńbà 20:20, 21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Síbẹ̀ ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ kọjá.”+ Ni Édómù bá kó ọ̀pọ̀ èèyàn àti àwọn ọmọ ogun tó lágbára* jáde wá pàdé rẹ̀. 21 Bí Édómù kò ṣe jẹ́ kí Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ òun kọjá nìyẹn; torí náà, Ísírẹ́lì yí pa dà lọ́dọ̀ rẹ̀.+

  • Sáàmù 83:4-6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Wọ́n sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa wọ́n run kí wọ́n má ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,+

      Kí a má sì rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.”

       5 Wọ́n fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tí wọ́n máa ṣe;*

      Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀* láti bá ọ jà,+

       6 Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, Móábù+ àti àwọn ọmọ Hágárì,+

  • Sáàmù 137:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Jèhófà, jọ̀wọ́ rántí

      Ohun tí àwọn ọmọ Édómù sọ lọ́jọ́ tí Jerúsálẹ́mù ṣubú, wọ́n ní:

      “Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”+

  • Jóẹ́lì 3:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Àmọ́ Íjíbítì yóò di ahoro,+

      Édómù yóò sì di aginjù tó dá páropáro,+

      Torí bí wọ́n ṣe hùwà ipá sí àwọn ará Júdà,+

      Ilẹ̀ àwọn tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.+

  • Émọ́sì 1:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

      ‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Édómù+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,

      Nítorí ó fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,+

      Àti nítorí pé ó kọ̀ láti ṣàánú rẹ̀;

      Ó ń fi ìbínú rẹ̀ fà wọ́n ya láìdáwọ́ dúró,

      Kò sì yéé bínú sí wọn.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́