ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 1 Kọ́ríńtì 1:1-16:24
  • 1 Kọ́ríńtì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1 Kọ́ríńtì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kọ́ríńtì

ÌWÉ KÌÍNÍ SÍ ÀWỌN ARÁ KỌ́RÍŃTÌ

1 Pọ́ọ̀lù, tí a pè láti jẹ́ àpọ́sítélì+ Kristi Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú Sótínésì arákùnrin wa, 2 sí ìjọ Ọlọ́run tó wà ní Kọ́ríńtì,+ sí ẹ̀yin tí a ti sọ di mímọ́ nínú Kristi Jésù,+ tí a pè láti jẹ́ ẹni mímọ́, ẹ̀yin àti gbogbo àwọn tó ń ké pe orúkọ Olúwa wa, Jésù Kristi+ níbi gbogbo, ẹni tó jẹ́ Olúwa wa àti tiwọn:

3 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín.

4 Ìgbà gbogbo ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nítorí yín lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fún yín nípasẹ̀ Kristi Jésù; 5 torí Ọlọ́run ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo nítorí rẹ̀, ẹ ti lè sọ̀rọ̀ dáadáa, ẹ sì ti ní ìmọ̀ tó kún rẹ́rẹ́,+ 6 gẹ́gẹ́ bí a ṣe fìdí ẹ̀rí nípa Kristi+ múlẹ̀ láàárín yín, 7 kí ẹ má bàa ṣaláìní ẹ̀bùn èyíkéyìí, bí ẹ ṣe ń dúró de ìfihàn Olúwa wa Jésù Kristi+ lójú méjèèjì. 8 Bákan náà, á mú kí ẹ dúró gbọn-in títí dé òpin, kí ẹ̀sùn kankan má bàa wà lọ́rùn yín ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kristi.+ 9 Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́,+ ẹni tó pè yín sínú àjọṣe* pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi Olúwa wa.

10 Ní báyìí, mo fi orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, pé kí gbogbo yín máa fohùn ṣọ̀kan àti pé kí ìyapa má ṣe sí láàárín yín,+ àmọ́ kí ẹ ní inú kan náà àti èrò kan náà.+ 11 Nítorí àwọn kan láti ilé Kílóè ti sọ fún mi nípa yín, ẹ̀yin ará mi, pé ìyapa wà láàárín yín. 12 Ohun tí mo ní lọ́kàn ni pé, kálukú yín ń sọ pé: “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” “Èmi jẹ́ ti Àpólò,”+ “Èmi jẹ́ ti Kéfà,”* “Èmi jẹ́ ti Kristi.” 13 Ṣé Kristi pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni? Wọn ò kan Pọ́ọ̀lù mọ́gi* fún yín, àbí òun ni wọ́n kàn? Àbí ṣé a batisí yín ní orúkọ Pọ́ọ̀lù ni? 14 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé mi ò batisí ìkankan lára yín àfi Kírípọ́sì+ àti Gáyọ́sì,+ 15 kí ẹnì kankan má bàa sọ pé a batisí yín ní orúkọ mi. 16 Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún batisí agbo ilé Sítéfánásì.+ Àmọ́ ní ti àwọn tó kù, mi ò mọ̀ bóyá mo batisí ẹnì kankan nínú wọn. 17 Nítorí Kristi ò rán mi pé kí n lọ máa batisí, iṣẹ́ kíkéde ìhìn rere ló rán mi;+ kì í sì í ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀rọ̀ sísọ,* kí a má bàa sọ igi oró* Kristi di ohun tí kò wúlò.

18 Torí ọ̀rọ̀ nípa igi oró* jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú àwọn tó ń ṣègbé,+ àmọ́ lójú àwa tí à ń gbà là, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run.+ 19 Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Màá mú kí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ṣègbé, làákàyè àwọn amòye ni màá sì kọ̀ sílẹ̀.”*+ 20 Ibo ni ọlọ́gbọ́n wà? Ibo ni akọ̀wé òfin* wà? Ibo ni òjiyàn ọ̀rọ̀ ètò àwọn nǹkan yìí* wà? Ṣé Ọlọ́run kò ti sọ ọgbọ́n ayé di òmùgọ̀ ni? 21 Torí nígbà tó ti jẹ́ pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò fi ọgbọ́n tirẹ̀+ mọ Ọlọ́run,+ inú Ọlọ́run dùn sí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀+ tí à ń wàásù láti gba àwọn tó nígbàgbọ́ là.

22 Nítorí àwọn Júù ń béèrè àmì,+ àwọn Gíríìkì sì ń wá ọgbọ́n; 23 àmọ́ àwa ń wàásù Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi,* lójú àwọn Júù, ó jẹ́ ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ àmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ó jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.+ 24 Ṣùgbọ́n lójú àwọn tí a pè, ì báà jẹ́ Júù tàbí Gíríìkì, Kristi ni agbára Ọlọ́run àti ọgbọ́n Ọlọ́run.+ 25 Nítorí ohun òmùgọ̀ ti Ọlọ́run gbọ́n ju èèyàn lọ, ohun aláìlera ti Ọlọ́run sì lágbára ju èèyàn lọ.+

26 Nítorí ẹ rí bó ṣe pè yín, ẹ̀yin ará, pé kì í ṣe ọ̀pọ̀ ọlọ́gbọ́n nípa ti ara* ni a pè,+ kì í ṣe ọ̀pọ̀ alágbára, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn tí a bí ní ilé ọlá,*+ 27 àmọ́, Ọlọ́run yan àwọn ohun òmùgọ̀ ayé, kí ó lè dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì yan àwọn ohun aláìlera ayé, kí ó lè dójú ti àwọn ohun tó lágbára;+ 28 Ọlọ́run yan àwọn ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan nínú ayé àti àwọn ohun tí wọ́n ń fojú àbùkù wò, àwọn ohun tí kò sí, kí ó lè sọ àwọn ohun tó wà di asán,+ 29 kí ẹnì* kankan má bàa yangàn níwájú Ọlọ́run. 30 Ṣùgbọ́n òun ló mú kí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù, ẹni tó fi ọgbọ́n Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀+ hàn wá, ó sọ wá di mímọ́,+ ó sì tú wa sílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà,+ 31 kí ó lè rí bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹni tó bá ń yangàn, kó máa yangàn nínú Jèhófà.”*+

2 Torí náà, nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín, ẹ̀yin ará, mi ò wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kàbìtì-kàbìtì+ tàbí ọgbọ́n láti kéde àṣírí mímọ́+ Ọlọ́run fún yín. 2 Nítorí mo ti pinnu pé mi ò ní sọ̀rọ̀ nípa ohun míì láàárín yín àfi nípa Jésù Kristi, ẹni tí wọ́n kàn mọ́gi.*+ 3 Nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín, ara mi ò le, ẹ̀rù ń bà mí, jìnnìjìnnì sì bá mi; 4 nígbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀ tí mo sì ń wàásù, kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtì-kàbìtì tí àwọn ọlọ́gbọ́n ń lò ni mò ń sọ, àmọ́ ọ̀rọ̀ mi ń fi agbára ẹ̀mí mímọ́ hàn,+ 5 kí ẹ má bàa gbé ìgbàgbọ́ yín ka ọgbọ́n èèyàn, bí kò ṣe agbára Ọlọ́run.

6 Ní báyìí, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàárín àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí,+ àmọ́ kì í ṣe ọgbọ́n ètò àwọn nǹkan yìí* tàbí ti àwọn alákòóso ètò àwọn nǹkan yìí, àwọn tó máa di asán.+ 7 Àmọ́ à ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọ́run nínú àṣírí mímọ́,+ tó jẹ́ ọgbọ́n tí a fi pa mọ́, èyí tí Ọlọ́run ti yàn ṣáájú àwọn ètò àwọn nǹkan fún ògo wa. 8 Kò sí ìkankan nínú àwọn alákòóso ètò àwọn nǹkan yìí* tó mọ ọgbọ́n yìí,+ torí ká ní wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn ì bá má pa Olúwa ológo.* 9 Àmọ́, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ojú kò tíì rí, etí kò sì tíì gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn èèyàn kò tíì ro àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”+ 10 Nítorí àwa ni Ọlọ́run ti ṣí wọn payá fún+ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀,+ nítorí ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, títí kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.+

11 Nítorí ta ló lè mọ ohun tí ẹnì kan ń rò àfi* onítọ̀hún? Bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ẹni tó mọ àwọn nǹkan ti Ọlọ́run, àfi ẹ̀mí Ọlọ́run. 12 Ní báyìí, kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ kí a lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fi ṣe wá lóore. 13 Àwọn nǹkan yìí ni àwa náà ń sọ, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi kọ́ni nípa ọgbọ́n èèyàn,+ bí kò ṣe pẹ̀lú àwọn tí a fi kọ́ni nípasẹ̀ ẹ̀mí,+ bí a ṣe ń fi àwọn ọ̀rọ̀ tẹ̀mí ṣàlàyé àwọn nǹkan tẹ̀mí.*

14 Ẹni ti ara kì í tẹ́wọ́ gba* àwọn nǹkan ti ẹ̀mí Ọlọ́run, torí wọ́n jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lójú rẹ̀; kò sì lè mọ̀ wọ́n, nítorí ẹ̀mí la fi ń wádìí wọn. 15 Àmọ́ ẹni tẹ̀mí máa ń wádìí ohun gbogbo,+ ṣùgbọ́n èèyàn èyíkéyìí kì í wádìí òun fúnra rẹ̀. 16 Nítorí “ta ló ti wá mọ èrò inú Jèhófà,* kí ó lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?”+ Àmọ́ àwa ní èrò inú Kristi.+

3 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, mi ò lè bá yín sọ̀rọ̀ bí ẹní ń bá àwọn ẹni tẹ̀mí sọ̀rọ̀,+ àmọ́ bí ẹní ń bá àwọn ẹni ti ara sọ̀rọ̀, bí ẹní ń bá àwọn ìkókó+ nínú Kristi sọ̀rọ̀. 2 Wàrà ni mo fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ líle, torí nígbà yẹn, ẹ ò tíì lágbára tó. Kódà ní báyìí, ẹ ò tíì lágbára tó,+ 3 nítorí ẹ ṣì jẹ́ ẹni ti ara.+ Nígbà tí owú àti wàhálà wà láàárín yín, ṣé ẹ kì í ṣe ẹni ti ara ni,+ ṣé ẹ kì í sì í ṣe bí àwọn èèyàn ayé ni? 4 Torí nígbà tí ẹnì kan bá sọ pé, “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” tí òmíràn sì sọ pé, “Èmi jẹ́ ti Àpólò,”+ ṣé kì í ṣe ìwà àwọn èèyàn ayé lẹ̀ ń hù yẹn?

5 Kí wá ni Àpólò jẹ́? Kí sì ni Pọ́ọ̀lù jẹ́? Àwọn òjíṣẹ́+ tí ẹ tipasẹ̀ wọn di onígbàgbọ́, bí Olúwa ṣe fún kálukú láǹfààní. 6 Èmi gbìn,+ Àpólò bomi rin,+ àmọ́ Ọlọ́run ló mú kó máa dàgbà, 7 tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tó ń gbìn ló ṣe pàtàkì tàbí ẹni tó ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tó ń mú kó dàgbà.+ 8 Ní báyìí, ọ̀kan náà ni ẹni tó ń gbìn àti ẹni tó ń bomi rin jẹ́,* àmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan máa gba èrè iṣẹ́ tirẹ̀.+ 9 Nítorí alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá. Ẹ̀yin jẹ́ pápá Ọlọ́run tí à ń ro lọ́wọ́, ilé Ọlọ́run.+

10 Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fún mi, mo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá kọ́lékọ́lé tó mọṣẹ́,* àmọ́ ẹlòmíì ń kọ́lé sórí rẹ̀. Kí kálukú máa ṣọ́ bó ṣe ń kọ́lé sórí rẹ̀. 11 Nítorí kò sí ẹni tó lè fi ìpìlẹ̀ èyíkéyìí míì lélẹ̀ ju ohun tí a ti fi lélẹ̀, ìyẹn Jésù Kristi.+ 12 Ní báyìí, tí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ wúrà, fàdákà, àwọn òkúta iyebíye, igi, koríko gbígbẹ tàbí pòròpórò sórí ìpìlẹ̀ náà, 13 ohun tí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ á hàn,* torí ọjọ́ náà yóò tú u síta, nítorí iná yóò fi í hàn,+ iná náà yóò sì fi ohun tí kálukú fi kọ́lé hàn. 14 Bí ohun tí ẹnì kan kọ́ sórí rẹ̀ bá dúró, ẹni náà yóò gba èrè; 15 bí iṣẹ́ ẹnì kan bá jóná, ẹni náà yóò pàdánù, àmọ́ a ó gba òun fúnra rẹ̀ là; síbẹ̀, tó bá rí bẹ́ẹ̀, á dà bí ìgbà téèyàn la iná kọjá.

16 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run+ àti pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín?+ 17 Tí ẹnikẹ́ni bá pa tẹ́ńpìlì Ọlọ́run run, Ọlọ́run á pa ẹni náà run; nítorí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin sì ni tẹ́ńpìlì yẹn.+

18 Kí ẹnì kankan má tan ara rẹ̀ jẹ: Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá rò pé òun gbọ́n nínú ètò àwọn nǹkan yìí,* kí ó di òmùgọ̀, kí ó lè gbọ́n. 19 Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, torí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “Ó ń mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn.”+ 20 Àti pé: “Jèhófà* mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”+ 21 Torí náà, kí ẹnì kankan má ṣe máa fi èèyàn yangàn; nítorí ohun gbogbo jẹ́ tiyín, 22 ì báà jẹ́ Pọ́ọ̀lù tàbí Àpólò tàbí Kéfà*+ tàbí ayé tàbí ìyè tàbí ikú tàbí àwọn ohun tó wà níbí nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀, ohun gbogbo jẹ́ tiyín; 23 ẹ̀yin náà jẹ́ ti Kristi;+ Kristi ní tirẹ̀ jẹ́ ti Ọlọ́run.

4 Ó yẹ kí àwọn èèyàn kà wá sí ìránṣẹ́* Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí mímọ́ Ọlọ́run.+ 2 Nínú ọ̀rọ̀ yìí, ohun tí à ń retí lọ́dọ̀ àwọn ìríjú ni pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. 3 Lójú tèmi, kò jẹ́ nǹkan kan pé kí ẹ̀yin tàbí àwùjọ ìgbẹ́jọ́* téèyàn gbé kalẹ̀ wádìí mi wò. Kódà, èmi gan-an kò wádìí ara mi wò. 4 Nítorí mi ò rí nǹkan tó burú nínú ohun tí mo ṣe. Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé mo jẹ́ olódodo; ẹni tó ń wádìí mi wò ni Jèhófà.*+ 5 Nítorí náà, ẹ má ṣèdájọ́+ ohunkóhun ṣáájú àkókò tó yẹ, títí Olúwa yóò fi dé. Yóò mú àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ inú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀, á sì jẹ́ kí a mọ èrò ọkàn àwọn èèyàn, lẹ́yìn náà, kálukú á gba ìyìn rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+

6 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo ti fi èmi àti Àpólò+ ṣàpẹẹrẹ* àwọn nǹkan yìí fún ire yín, kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ wa, ẹ máa kọ́ ìlànà tó sọ pé: “Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀,” kí ẹ má bàa gbéra ga,+ tí ẹ ó sì máa sọ pé ẹnì kan dára ju èkejì lọ. 7 Nítorí ta ló mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Ní tòótọ́, kí lo ní tí kì í ṣe pé o gbà á?+ Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo gbà á lóòótọ́, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu bíi pé kì í ṣe pé o gbà á?

8 Ṣé ó ti tẹ́ yín lọ́rùn báyìí? Ṣé ẹ ti lọ́rọ̀ báyìí? Ṣé ẹ ti ń ṣàkóso bí ọba+ láìsí àwa? Ì bá wù mí kí ẹ ti máa ṣàkóso bí ọba, kí àwa náà lè ṣàkóso pẹ̀lú yín bí ọba.+ 9 Nítorí lójú tèmi, ó dà bíi pé Ọlọ́run ti fi àwa àpọ́sítélì sí ìgbẹ̀yìn láti fi wá hàn bí àwọn tí a ti dájọ́ ikú fún,+ nítorí a ti di ìran àpéwò fún ayé+ àti fún àwọn áńgẹ́lì àti fún àwọn èèyàn. 10 Àwa jẹ́ òmùgọ̀+ nítorí Kristi, àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ olóye nínú Kristi; àwa jẹ́ aláìlera, àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ alágbára; ẹ̀yin ní iyì, àmọ́ àwa kò ní iyì. 11 Títí di wákàtí yìí, ebi ń pa wá,+ òùngbẹ ń gbẹ wá,+ a ò rí aṣọ tó dáa wọ̀,* wọ́n ń nà wá,*+ a ò sì rí ilé gbé, 12 à ń ṣe làálàá, a sì ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́.+ Nígbà tí wọ́n ń bú wa, à ń súre;+ nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, à ń fara dà á pẹ̀lú sùúrù;+ 13 nígbà tí wọ́n bà wá lórúkọ jẹ́, a fi ohùn pẹ̀lẹ́ dáhùn;*+ a ti dà bíi pàǹtírí* ayé, èérí ohun gbogbo, títí di báyìí.

14 Kì í ṣe kí n lè dójú tì yín ni mo ṣe ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín, àmọ́ kí n lè gbà yín níyànjú bí àwọn ọmọ mi tó jẹ́ àyànfẹ́. 15 Nítorí bí ẹ bá tiẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) atọ́nisọ́nà* nínú Kristi, ẹ kò ní baba púpọ̀; torí nínú Kristi Jésù, mo di baba yín nípasẹ̀ ìhìn rere.+ 16 Nítorí náà, mo rọ̀ yín, ẹ máa fara wé mi.+ 17 Ìdí nìyẹn tí mo fi rán Tímótì sí yín, torí ó jẹ́ ọmọ mi ọ̀wọ́n àti olóòótọ́ nínú Olúwa. Á rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mò ń gbà ṣe nǹkan* ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù,+ bí mo ṣe ń kọ́ni níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ.

18 Àwọn kan ń gbéra ga, bíi pé mi ò ní wá sọ́dọ̀ yín. 19 Àmọ́ màá wá sọ́dọ̀ yín láìpẹ́, tí Jèhófà* bá fẹ́, kí n lè mọ agbára tí àwọn tó ń gbéra ga ní, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. 20 Nítorí Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu, ti agbára ni. 21 Èwo lẹ fẹ́? Ṣé kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú ọ̀pá+ àbí kí n wá pẹ̀lú ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìwà tútù?

5 Ní tòótọ́, wọ́n ròyìn ìṣekúṣe*+ tó ṣẹlẹ̀ láàárín yín, irú ìṣekúṣe* bẹ́ẹ̀ kò tiẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé ọkùnrin kan ń fẹ́* ìyàwó bàbá rẹ̀.+ 2 Ṣé ẹ wá ń fìyẹn yangàn ni? Ṣé kì í ṣe pé ó yẹ kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀+ kí a lè mú ọkùnrin tó ṣe nǹkan yìí kúrò láàárín yín?+ 3 Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa tara, mo wà lọ́dọ̀ yín nípa tẹ̀mí, mo sì ti ṣèdájọ́ ọkùnrin tó ṣe nǹkan yìí, bíi pé èmi fúnra mi wà lọ́dọ̀ yín. 4 Nígbà tí ẹ bá pé jọ ní orúkọ Olúwa wa Jésù, tí ẹ sì mọ̀ pé mo wà pẹ̀lú yín nípa tẹ̀mí nínú agbára Olúwa wa Jésù, 5 kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé Sátánì lọ́wọ́+ kí agbára ẹ̀ṣẹ̀ náà lè pa run, kí ipò tẹ̀mí ìjọ lè wà láìyingin ní ọjọ́ Olúwa.+

6 Bí ẹ ṣe ń fọ́nnu yìí kò dáa. Ṣé ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú ni?+ 7 Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè di ìṣùpọ̀ tuntun, tí kò bá ti sí amóhunwú nínú yín. Torí, ní tòótọ́, a ti fi Kristi ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá wa+ rúbọ.+ 8 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe àjọyọ̀,+ kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú, àmọ́ ká ṣe é pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú ti òótọ́ inú àti ti òtítọ́.

9 Nínú lẹ́tà tí mo kọ sí yín, mo ní kí ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́* pẹ̀lú àwọn oníṣekúṣe,* 10 àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn oníṣekúṣe* ayé yìí+ tàbí àwọn olójúkòkòrò tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà tàbí àwọn abọ̀rìṣà ni mò ń sọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, á di pé kí ẹ kúrò nínú ayé.+ 11 Ṣùgbọ́n ní báyìí mò ń kọ̀wé sí yín pé kí ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́*+ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, àmọ́ tó jẹ́ oníṣekúṣe* tàbí olójúkòkòrò+ tàbí abọ̀rìṣà tàbí pẹ̀gànpẹ̀gàn* tàbí ọ̀mùtípara+ tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà,+ kí ẹ má tiẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun. 12 Torí kí ló kàn mí pẹ̀lú ṣíṣèdájọ́ àwọn tó wà lóde? Ṣebí àwọn tó wà nínú ìjọ lẹ̀ ń dá lẹ́jọ́, 13 nígbà tí Ọlọ́run ń dá àwọn tó wà lóde lẹ́jọ́?+ “Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò láàárín yín.”+

6 Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú yín tó ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan+ gbójúgbóyà lọ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìṣòdodo, tí kì í sì í ṣe níwájú àwọn ẹni mímọ́? 2 Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ló máa ṣèdájọ́ ayé?+ Tó bá sì jẹ́ pé ẹ̀yin lẹ máa ṣèdájọ́ ayé, ṣé ẹ ò mọ bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ lórí àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan ni? 3 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé àwa la máa ṣèdájọ́ àwọn áńgẹ́lì ni?+ Kí ló wá dé tí a ò lè yanjú àwọn ọ̀ràn ti ayé yìí? 4 Tí ẹ bá wá ní àwọn ọ̀ràn ayé yìí tí ẹ fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀,+ ṣé àwọn ọkùnrin tí ìjọ ń fojú àbùkù wò ló yẹ kí ẹ yàn ṣe onídàájọ́? 5 Mò ń sọ̀rọ̀ kí ojú lè tì yín. Ṣé kò sí ọlọ́gbọ́n kankan láàárín yín tó lè ṣèdájọ́ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀ ni? 6 Arákùnrin wá ń gbé arákùnrin lọ sí ilé ẹjọ́, ó tún wá jẹ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́!

7 Ní tòótọ́, ẹ ti pa ara yín láyò bí ẹ ṣe ń pe ara yín lẹ́jọ́. Ẹ ò ṣe kúkú gbà kí wọ́n ṣe àìtọ́ sí yín?+ Ẹ ò ṣe kúkú jẹ́ kí wọ́n lù yín ní jìbìtì? 8 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń ṣe àìtọ́, ẹ sì ń lu jìbìtì, ó tún wá jẹ́ sí àwọn arákùnrin yín!

9 Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run ni?+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣì yín lọ́nà.* Àwọn oníṣekúṣe,*+ àwọn abọ̀rìṣà,+ àwọn alágbèrè,+ àwọn ọkùnrin tó ń jẹ́ kí ọkùnrin bá wọn lò pọ̀,+ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀,*+ 10 àwọn olè, àwọn olójúkòkòrò,+ àwọn ọ̀mùtípara,+ àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn* àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+ 11 Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ a ti wẹ̀ yín mọ́;+ a ti yà yín sí mímọ́;+ a ti pè yín ní olódodo+ ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run wa.

12 Ohun gbogbo ló bófin mu* lójú mi, àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ṣàǹfààní.+ Ohun gbogbo ló bófin mu lójú mi, àmọ́ mi ò ní jẹ́ kí ohunkóhun máa darí mi.* 13 Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ, àmọ́ Ọlọ́run máa sọ àwọn méjèèjì di asán.+ Ara kò wà fún ìṣekúṣe,* Olúwa ló wà fún,+ Olúwa sì wà fún ara. 14 Àmọ́ Ọlọ́run gbé Olúwa dìde,+ yóò sì gbé àwa náà dìde kúrò nínú ikú+ nípasẹ̀ agbára rẹ̀.+

15 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni ara yín ni?+ Ṣé ó wá yẹ kí n mú ẹ̀yà ara Kristi kúrò, kí n sì dà á pọ̀ mọ́ ti aṣẹ́wó? Ká má ri! 16 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹni tó bá ní àṣepọ̀ pẹ̀lú aṣẹ́wó á di ara kan pẹ̀lú rẹ̀ ni? Nítorí Ọlọ́run sọ pé “àwọn méjèèjì á sì di ara kan.”+ 17 Àmọ́ ẹni tó bá dara pọ̀ mọ́ Olúwa jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ nínú ẹ̀mí.+ 18 Ẹ máa sá fún ìṣekúṣe!*+ Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ míì tí èèyàn lè dá wà lóde ara rẹ̀, àmọ́ ẹni tó bá ń ṣe ìṣekúṣe ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.+ 19 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ara yín ni tẹ́ńpìlì+ ẹ̀mí mímọ́ tó wà nínú yín, èyí tí ẹ gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run?+ Bákan náà, ẹ kì í ṣe ti ara yín,+ 20 nítorí a ti rà yín ní iye kan.+ Nítorí náà, ẹ máa yin Ọlọ́run lógo+ nínú ara yín.+

7 Ní báyìí, ní ti àwọn ohun tí ẹ kọ̀wé nípa rẹ̀, ó sàn kí ọkùnrin má fọwọ́ kan* obìnrin; 2 àmọ́ nítorí ìṣekúṣe* tó gbòde kan, kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ní aya tirẹ̀,+ kí obìnrin kọ̀ọ̀kan sì ní ọkọ tirẹ̀.+ 3 Kí ọkọ máa fún aya rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ rẹ̀, kí aya sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.+ 4 Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀, ọkọ rẹ̀ ló láṣẹ; bákan náà, ọkọ kò láṣẹ lórí ara rẹ̀, aya rẹ̀ ló láṣẹ. 5 Ẹ má ṣe máa fi du ara yín àfi tó bá jẹ́ àjọgbà fún àkókò kan, kí ẹ lè ya àkókò sọ́tọ̀ fún àdúrà, kí ẹ sì pa dà wà pa pọ̀, kí Sátánì má bàa máa dẹ yín wò torí pé ẹ ò lè mára dúró. 6 Àmọ́, mi ò pa á láṣẹ o, mo kàn ń sọ ohun tí ẹ lè ṣe ni. 7 Ì bá wù mí kí gbogbo èèyàn dà bíi tèmi. Síbẹ̀, kálukú ló ní ẹ̀bùn tirẹ̀+ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọ̀kan lọ́nà yìí, òmíràn lọ́nà yẹn.

8 Tóò, mo sọ fún àwọn tí kò gbéyàwó àti àwọn opó pé ó sàn kí wọ́n wà bí mo ṣe wà.+ 9 Àmọ́ tí wọn ò bá lè mára dúró, kí wọ́n gbéyàwó, torí ó sàn láti gbéyàwó ju kí ara ẹni máa gbóná nítorí ìfẹ́ ìbálòpọ̀.+

10 Mo fún àwọn tó ti ṣègbéyàwó ní ìtọ́sọ́nà, àmọ́ kì í ṣe èmi, Olúwa ni, pé kí aya má ṣe kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀.+ 11 Àmọ́ tó bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó wà láìlọ́kọ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ kó pa dà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀.+

12 Àmọ́ mo sọ fún àwọn yòókù, bẹ́ẹ̀ ni, èmi ni, kì í ṣe Olúwa+ pé: Tí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, tí obìnrin náà sì gbà láti máa bá a gbé, kí ó má fi obìnrin náà sílẹ̀; 13 tí obìnrin kan bá sì ní ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, tí ọkùnrin náà gbà láti máa bá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. 14 Nítorí ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ni a sọ di mímọ́ nítorí aya rẹ̀, aya tó sì jẹ́ aláìgbàgbọ́ ni a sọ di mímọ́ nítorí arákùnrin náà; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ yín á jẹ́ aláìmọ́, àmọ́ ní báyìí wọ́n jẹ́ mímọ́. 15 Ṣùgbọ́n tí aláìgbàgbọ́ náà bá pinnu láti lọ,* jẹ́ kó máa lọ; irú ipò bẹ́ẹ̀ kò de arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, àmọ́ Ọlọ́run ti pè yín sí àlàáfíà.+ 16 Ìwọ aya, ṣé o mọ̀ bóyá wàá gba ọkọ rẹ là?+ Ìwọ ọkọ, ṣé o mọ̀ bóyá wàá gba aya rẹ là?

17 Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà* ṣe fún kálukú ní ìpín tirẹ̀, kí kálukú máa rìn bí Ọlọ́run ṣe pè é.+ Torí náà, mo fi àṣẹ yìí lélẹ̀ nínú gbogbo ìjọ. 18 Ǹjẹ́ ọkùnrin kan wà tó ti dádọ̀dọ́* nígbà tí a pè é?+ Kí ó má pa dà di aláìdádọ̀dọ́.* Ǹjẹ́ ọkùnrin kan wà tó jẹ́ aláìdádọ̀dọ́ nígbà tí a pè é? Kí ó má ṣe dádọ̀dọ́.+ 19 Ìdádọ̀dọ́* kò túmọ̀ sí nǹkan kan, àìdádọ̀dọ́* kò sì túmọ̀ sí nǹkan kan;+ pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ni ohun tó ṣe pàtàkì.+ 20 Ipòkípò tí kálukú wà nígbà tí a pè é, kí ó wà bẹ́ẹ̀.+ 21 Ṣé ẹrú ni ọ́ nígbà tí a pè ọ́? Má ṣe jẹ́ kí ìyẹn dà ọ́ láàmú;+ àmọ́ tí o bá lè di òmìnira, tètè gbá àǹfààní náà mú. 22 Nítorí ẹnikẹ́ni tí a pè nínú Olúwa nígbà tó jẹ́ ẹrú ti di òmìnira nínú Olúwa; + bákan náà, ẹnikẹ́ni tí a pè nígbà tó wà ní òmìnira jẹ́ ẹrú Kristi. 23 A ti rà yín ní iye kan;+ ẹ má ṣe ẹrú èèyàn mọ́. 24 Ipòkípò tí kálukú wà nígbà tí a pè é, ẹ̀yin ará, kí ó wà bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

25 Ní ti àwọn wúńdíá,* mi ò ní àṣẹ kankan látọ̀dọ̀ Olúwa, àmọ́ mo sọ èrò mi+ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Olúwa fi àánú hàn sí láti jẹ́ olóòótọ́. 26 Nítorí náà, mo rò pé ohun tó dáa jù lọ ni pé kí ọkùnrin kan wà bó ṣe wà nítorí ìṣòro ìsinsìnyí. 27 Ṣé o ti gbéyàwó? Má ṣe wá ọ̀nà láti fi í sílẹ̀.+ Ṣé o ò níyàwó mọ́? Má ṣe máa wá ìyàwó. 28 Àmọ́ tí o bá tiẹ̀ gbéyàwó, o ò dẹ́ṣẹ̀ kankan. Tí wúńdíá kan bá sì ṣègbéyàwó, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò dẹ́ṣẹ̀ kankan. Síbẹ̀, àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ máa ní ìpọ́njú nínú ara wọn. Àmọ́ mi ò fẹ́ kí ẹ kó sínú ìṣòro.

29 Yàtọ̀ síyẹn, mo sọ èyí, ẹ̀yin ará, pé àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù.+ Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn tó níyàwó dà bíi pé wọn kò ní, 30 kí àwọn tó ń sunkún dà bí àwọn tí kò sunkún, kí àwọn tó ń yọ̀ dà bí àwọn tí kò yọ̀, kí àwọn tó ń rà dà bí àwọn tí kò ní, 31 kí àwọn tó ń lo ayé dà bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí* ayé yìí ń yí pa dà. 32 Ní tòótọ́, mi ò fẹ́ kí ẹ máa ṣàníyàn. Ọkùnrin tí kò gbéyàwó máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti Olúwa, bó ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà Olúwa. 33 Àmọ́ ọkùnrin tó gbéyàwó máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti ayé,+ bó ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀, 34 ó sì ní ìpínyà ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, obìnrin tí kò lọ́kọ àti wúńdíá, máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti Olúwa,+ kí ó lè jẹ́ mímọ́ nínú ara àti nínú ẹ̀mí. Àmọ́, obìnrin tó ti lọ́kọ máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ti ayé, bó ṣe máa rí ìtẹ́wọ́gbà ọkọ rẹ̀. 35 mò ń sọ èyí nítorí àǹfààní ara yín, kì í ṣe kí n lè dín òmìnira yín kù,* àmọ́ kí n lè mú kí ẹ ṣe ohun tí ó tọ́, kí ẹ sì lè gbájú mọ́ iṣẹ́ Olúwa láìsí ìpínyà ọkàn.

36 Àmọ́ tí ẹnì kan bá rí i pé òun ti ń hùwà tí kò yẹ torí pé òun kò gbéyàwó,* tí onítọ̀hún sì ti kọjá ìgbà ìtànná èwe,* ohun tó yẹ kó ṣe nìyí: Kí ó ṣe ohun tí ó fẹ́; kò dẹ́ṣẹ̀. Kí wọ́n gbéyàwó.+ 37 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, tí kò sì sídìí tó fi gbọ́dọ̀ yí i pa dà, ṣùgbọ́n tó ní àṣẹ lórí ohun tó fẹ́, tó sì ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀ láti wà láìgbéyàwó,* yóò ṣe dáadáa.+ 38 Bákan náà, ẹni tó bá gbéyàwó* ṣe dáadáa, àmọ́ ẹni tí kò bá gbéyàwó ṣe dáadáa jù.+

39 Òfin de aya ní gbogbo ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè.+ Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá sùn nínú ikú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹni tó bá wù ú, kìkì nínú Olúwa.+ 40 Àmọ́ lérò tèmi, ó máa láyọ̀ jù tó bá wà bó ṣe wà; ó sì dá mi lójú pé èmi náà ní ẹ̀mí Ọlọ́run.

8 Ní báyìí, ní ti oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà:+ A mọ̀ pé gbogbo wa la ní ìmọ̀.+ Ìmọ̀ máa ń gbéra ga, àmọ́ ìfẹ́ ń gbéni ró.+ 2 Tí ẹnì kan bá rò pé òun mọ ohun kan, kò tíì mọ̀ ọ́n bó ṣe yẹ kó mọ̀ ọ́n. 3 Àmọ́ tí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run mọ ẹni náà.

4 Ní báyìí, ní ti jíjẹ oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé òrìṣà kò jẹ́ nǹkan kan+ nínú ayé àti pé kò sí Ọlọ́run míì àfi ọ̀kan ṣoṣo.+ 5 Torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí à ń pè ní ọlọ́run wà, ì báà jẹ́ ní ọ̀run tàbí ní ayé,+ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” àti ọ̀pọ̀ “olúwa” ṣe wà, 6 ní tiwa, Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà,+ Baba,+ ọ̀dọ̀ ẹni tí ohun gbogbo ti wá, tí àwa náà sì wà fún un;+ Olúwa kan ló wà, Jésù Kristi, ipasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo fi wà,+ tí àwa náà sì wà nípasẹ̀ rẹ̀.

7 Síbẹ̀, gbogbo èèyàn kọ́ ló mọ̀ bẹ́ẹ̀.+ Ní ti àwọn kan, torí pé òrìṣà ni wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń wo oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ bí ohun tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà,+ èyí sì ń da ẹ̀rí ọkàn wọn tí kò lágbára láàmú.*+ 8 Àmọ́ oúnjẹ kọ́ ló máa mú wa sún mọ́ Ọlọ́run;+ tí a kò bá jẹun, kò bù wá kù, tí a bá sì jẹun, kò sọ wá di ẹni ńlá.+ 9 Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyè sára, kí ẹ̀tọ́ tí ẹ ní láti yan ohun tó wù yín má di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera.+ 10 Nítorí bí ẹnì kan bá rí ìwọ tí o ní ìmọ̀ tí ò ń jẹun nínú tẹ́ńpìlì òrìṣà, ṣé kò ní mú kí ẹ̀rí ọkàn ẹni yẹn le débi pé á lọ jẹ oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà? 11 Torí náà, ìmọ̀ rẹ ló mú kí ẹni tó jẹ́ aláìlera ṣègbé, arákùnrin rẹ tí Kristi kú fún.+ 12 Tí ẹ bá ṣẹ àwọn arákùnrin yín lọ́nà yìí, tí ẹ sì kó bá ẹ̀rí ọkàn+ wọn tí kò lágbára, Kristi lẹ ṣẹ̀ sí. 13 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tí oúnjẹ bá máa mú arákùnrin mi kọsẹ̀, mi ò ní jẹ ẹran mọ́ láé, kí n má bàa mú arákùnrin mi kọsẹ̀.+

9 Ṣé mi ò lómìnira ni? Ṣé èmi kì í ṣe àpọ́sítélì ni? Ṣé mi ò rí Jésù Olúwa wa rí ni?+ Ṣé ẹ kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ mi nínú Olúwa ni? 2 Ká tiẹ̀ ní mi ò jẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn ẹlòmíì, ó dájú hán-ún pé mo jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún yín! Nítorí ẹ̀yin ni èdìdì tó jẹ́rìí sí i pé mo jẹ́ àpọ́sítélì nínú Olúwa.

3 Ohun tí mo fi gbèjà ara mi lọ́dọ̀ àwọn tó ń wádìí mi wò nìyí: 4 A ní ẹ̀tọ́* láti jẹ àti láti mu, àbí a kò ní? 5 A ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tó jẹ́ onígbàgbọ́*+ lẹ́yìn bíi ti àwọn àpọ́sítélì yòókù àti àwọn arákùnrin Olúwa + àti Kéfà,*+ àbí a kò ní? 6 Àbí ṣé èmi àti Bánábà+ nìkan ni kò ní ẹ̀tọ́ láti fi iṣẹ́ tí a fi ń gbọ́ bùkátà sílẹ̀ ni? 7 Ọmọ ogun wo ló ń ná owó ara rẹ̀ sórí iṣẹ́ tó ń ṣe? Ta ló ń gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ èso rẹ̀?+ Àbí ta ló ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran tí kì í jẹ lára wàrà agbo ẹran náà?

8 Ṣé èrò èèyàn ló mú kí n sọ àwọn nǹkan tí mò ń sọ ni? Ṣé Òfin kò sọ bákan náà ni? 9 Torí ó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè pé: “O ò gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù nígbà tó bá ń pa ọkà.”+ Ṣé ti àwọn akọ màlúù ni Ọlọ́run ń rò ni? 10 Àbí torí wa ló ṣe sọ ọ́? Nítorí tiwa ló ṣe wà lákọsílẹ̀, torí ó yẹ kí ẹni tó ń túlẹ̀ àti ẹni tó ń pa ọkà máa retí pé wọ́n á pín nínú rẹ̀.

11 Tí a bá fúnrúgbìn nǹkan tẹ̀mí láàárín yín, ṣé ó pọ̀ jù ni tí a bá kórè nǹkan tara lọ́dọ̀ yín?+ 12 Tí àwọn míì bá ní ẹ̀tọ́ yìí lórí yín, ṣé èyí táwa ní kò ju tiwọn lọ fíìfíì ni? Síbẹ̀, a ò lo ẹ̀tọ́*+ yìí, àmọ́ à ń fara da ohun gbogbo ká má bàa dènà ìhìn rere nípa Kristi lọ́nàkọnà.+ 13 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ mímọ́ máa ń jẹ àwọn nǹkan tẹ́ńpìlì àti pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ máa ń gba ìpín nídìí pẹpẹ?+ 14 Lọ́nà yìí pẹ̀lú, Olúwa pàṣẹ pé kí àwọn tó ń kéde ìhìn rere máa jẹ nípasẹ̀ ìhìn rere.+

15 Àmọ́ mi ò tíì lo ìkankan nínú àwọn ìpèsè yìí.+ Ní tòótọ́, mi ò ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yìí torí kí a lè ṣe wọ́n fún mi, torí ó sàn kí n kú ju kí n jẹ́ kí ẹnì kan gba ẹ̀tọ́ tí mo ní láti ṣògo!+ 16 Ní báyìí, tí mo bá ń kéde ìhìn rere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa fi ṣògo, nítorí dandan ni fún mi. Ní tòótọ́, mo gbé tí mi ò bá kéde ìhìn rere! + 17 Tí mo bá ń ṣe é tinútinú, èrè wà fún mi; síbẹ̀ tí kò bá ti inú mi wá, iṣẹ́ ìríjú kan ṣì wà ní ìkáwọ́ mi.+ 18 Kí wá ni èrè mi? Òun ni pé nígbà tí mo bá ń kéde ìhìn rere, kí n lè máa kéde rẹ̀ láìgba owó, kí n má bàa ṣi àṣẹ* tí mo ní lórí ìhìn rere lò.

19 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò sí lábẹ́ ẹnì kankan, mo fi ara mi ṣe ẹrú gbogbo èèyàn, kí n lè jèrè ọ̀pọ̀ èèyàn tí mo bá lè jèrè. 20 Nítorí àwọn Júù, mo dà bíi Júù, kí n lè jèrè àwọn Júù;+ nítorí àwọn tó wà lábẹ́ òfin, mo dà bí ẹni tó wà lábẹ́ òfin, bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ò sí lábẹ́ òfin, kí n lè jèrè àwọn tó wà lábẹ́ òfin.+ 21 Nítorí àwọn tó wà láìní òfin mo dà bí aláìní òfin, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò wà láìní òfin sí Ọlọ́run, àmọ́ mo wà lábẹ́ òfin sí Kristi,+ kí n lè jèrè àwọn tó wà láìní òfin. 22 Nítorí àwọn aláìlera, mo di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera.+ Mo ti di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn, kí n lè gba àwọn kan là ní gbogbo ọ̀nà tí mo bá lè gbé e gbà. 23 Torí náà, mò ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì.+

24 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé nínú gbogbo àwọn tó ń sá eré ìje, ẹnì kan ló máa gba ẹ̀bùn ni? Ẹ sáré lọ́nà tí ẹ fi lè gbà á.+ 25 Gbogbo àwọn tó ń kópa nínú ìdíje* ló máa ń kíyè sára nínú ohun gbogbo. Lóòótọ́, wọ́n ń ṣe é kí wọ́n lè gba adé tó lè bà jẹ́,+ àmọ́ àwa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ká lè gba èyí tí kò lè bà jẹ́.+ 26 Nítorí náà, mi ò sáré láìnídìí,+ mi ò sì ju ẹ̀ṣẹ́ mi kí n lè máa gbá afẹ́fẹ́; 27 àmọ́ mò ń lu ara mi kíkankíkan,*+ mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, kó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíì, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà* lọ́nà kan ṣáá.

10 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn baba ńlá wa wà lábẹ́ ìkùukùu,*+ gbogbo wọn gba inú òkun kọjá,+ 2 a sì batisí gbogbo wọn láti jẹ́ ọmọlẹ́yìn Mósè nípasẹ̀ ìkùukùu* àti òkun, 3 gbogbo wọn jẹ oúnjẹ tẹ̀mí+ kan náà, 4 gbogbo wọn sì mu ohun mímu tẹ̀mí+ kan náà. Torí wọ́n ti máa ń mu látinú àpáta tẹ̀mí tó ń tẹ̀ lé wọn, àpáta náà sì dúró fún* Kristi.+ 5 Síbẹ̀, a pa wọ́n nínú aginjù+ nítorí inú Ọlọ́run kò dùn sí èyí tó pọ̀ jù lára wọn.

6 Àwọn nǹkan yìí di àpẹẹrẹ fún wa, kí àwọn ohun tó ń ṣeni léṣe má bàa máa wu àwa náà, bó ṣe wù wọ́n.+ 7 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe; gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Àwọn èèyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu. Wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.”+ 8 Bákan náà, kí a má ṣe ìṣekúṣe,* bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe ìṣekúṣe,* tí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000) lára wọn fi kú ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+ 9 Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe dán Jèhófà* wò,+ bí àwọn kan nínú wọn ṣe dán an wò, tí ejò sì ṣán wọn pa.+ 10 Bákan náà, kí ẹ má ṣe máa kùn, bí àwọn kan nínú wọn ṣe kùn,+ tí apanirun sì pa wọ́n.+ 11 Àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí wọn kí ó lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa,+ wọ́n sì wà lákọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.

12 Nítorí náà, kí ẹni tó bá rò pé òun dúró kíyè sára kó má bàa ṣubú.+ 13 Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.+ Àmọ́ Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra,+ ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.+

14 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.+ 15 Mo mọ̀ pé ẹ ní òye; ẹ fúnra yín pinnu lórí ohun tí mo sọ bóyá òótọ́ ni àbí irọ́. 16 Ife ìbùkún tí a súre sí, ṣebí láti pín nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi ni?+ Ìṣù búrẹ́dì tí a bù, ṣebí láti pín nínú ara Kristi ni?+ 17 Nítorí pé ìṣù búrẹ́dì kan ló wà, àwa, bí a tilẹ̀ pọ̀, a jẹ́ ara kan,+ torí gbogbo wa ló ń jẹ nínú ìṣù búrẹ́dì kan yẹn.

18 Ẹ wo Ísírẹ́lì lọ́nà ti ara: Ǹjẹ́ àwọn tó ń jẹ ohun tí a fi rúbọ kì í ṣe alájọpín pẹ̀lú pẹpẹ?+ 19 Kí ni mo wá ń sọ? Ṣé pé ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan ni? 20 Bẹ́ẹ̀ kọ́; àmọ́ ohun tí mò ń sọ ni pé àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ, àwọn ẹ̀mí èṣù ni wọ́n fi ń rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọ́run;+ mi ò sì fẹ́ kí ẹ di alájọpín pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù.+ 21 Ẹ ò lè máa mu nínú ife Jèhófà* àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù; ẹ ò lè máa jẹun lórí “tábìlì Jèhófà”*+ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù. 22 Àbí ‘ṣé a fẹ́ máa mú Jèhófà* jowú ni’?+ A ò lágbára jù ú lọ, àbí a ní?

23 Ohun gbogbo ló bófin mu,* àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ló bófin mu, àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ń gbéni ró.+ 24 Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.+

25 Ẹ máa jẹ ohunkóhun tí wọ́n ń tà ní ọjà ẹran, láìṣe ìwádìí kankan kí ẹ̀rí ọkàn yín má bàa dà yín láàmú, 26 nítorí pé “Jèhófà* ló ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀.”+ 27 Tí aláìgbàgbọ́ bá pè yín, tí ẹ sì fẹ́ lọ, ẹ jẹ ohunkóhun tó bá gbé síwájú yín, láìṣe ìwádìí kankan kí ẹ̀rí ọkàn yín má bàa dà yín láàmú. 28 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, “Ohun tí a fi rúbọ ni,” ẹ má ṣe jẹ ẹ́ nítorí ẹni tó sọ fún yín àti nítorí ẹ̀rí ọkàn.+ 29 Kì í ṣe ẹ̀rí ọkàn yín ni mò ń sọ, ti ẹni yẹn ni. Kí nìdí tí màá fi jẹ́ kí ẹnì kan fi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ dá mi lẹ́jọ́ lórí ohun tí mo lómìnira láti ṣe?+ 30 Tí mo bá ń jẹ ẹ́, tí mo sì ń dúpẹ́, kí nìdí tí a ó fi máa sọ̀rọ̀ mi láìdáa nítorí ohun tí mo dúpẹ́ lé lórí?+

31 Nítorí náà, bóyá ẹ̀ ń jẹ tàbí ẹ̀ ń mu tàbí ẹ̀ ń ṣe ohunkóhun míì, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.+ 32 Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹ má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì àti fún ìjọ Ọlọ́run,+ 33 bí mo ṣe ń gbìyànjú láti wu gbogbo èèyàn nínú ohun gbogbo, láìmáa wá ire ti ara mi+ bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ èèyàn, kí wọ́n lè rí ìgbàlà.+

11 Ẹ máa fara wé mi, bí èmi náà ṣe ń fara wé Kristi.+

2 Mo gbóríyìn fún yín nítorí nínú ohun gbogbo, ẹ̀ ń rántí mi, ẹ sì di àwọn àṣà tí mo fi lé yín lọ́wọ́ mú ṣinṣin. 3 Àmọ́ mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí gbogbo ọkùnrin ni Kristi; + bákan náà, orí obìnrin ni ọkùnrin;+ bákan náà, orí Kristi ni Ọlọ́run.+ 4 Gbogbo ọkùnrin tó ń gbàdúrà tàbí tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, tó sì fi nǹkan borí ń dójú ti orí rẹ̀; 5 àmọ́ gbogbo obìnrin tó ń gbàdúrà tàbí tó ń sọ tẹ́lẹ̀+ láìborí ń dójú ti orí rẹ̀, nítorí bákan náà ló rí pẹ̀lú obìnrin tó fárí. 6 Nítorí tí obìnrin kò bá borí, kí ó gé irun rẹ̀; àmọ́ tó bá jẹ́ ohun ìtìjú fún obìnrin láti gé irun tàbí kí ó fárí, ó yẹ kí ó borí.

7 Nítorí kò yẹ kí ọkùnrin borí, torí ó jẹ́ àwòrán+ àti ògo Ọlọ́run, àmọ́ obìnrin jẹ́ ògo ọkùnrin. 8 Torí ọkùnrin kò wá láti ara obìnrin, àmọ́ obìnrin wá láti ara ọkùnrin.+ 9 Àti pé, a kò dá ọkùnrin nítorí obìnrin, àmọ́ a dá obìnrin nítorí ọkùnrin.+ 10 Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí obìnrin ní àmì àṣẹ ní orí rẹ̀, nítorí àwọn áńgẹ́lì.+

11 Yàtọ̀ síyẹn, nínú Olúwa, kò sí obìnrin láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọkùnrin láìsí obìnrin. 12 Nítorí bí obìnrin ṣe wá láti ara ọkùnrin,+ bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin ṣe wá nípasẹ̀ obìnrin; àmọ́ ohun gbogbo wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 13 Ẹ fúnra yín pinnu: Ṣé ó yẹ kí obìnrin gbàdúrà sí Ọlọ́run láìborí? 14 Ṣé ìwà ẹ̀dá fúnra rẹ̀ kò kọ́ yín pé àbùkù ni irun gígùn jẹ́ fún ọkùnrin, 15 àmọ́ tí obìnrin bá ní irun gígùn, ògo ni ó jẹ́ fún un? Nítorí irun rẹ̀ ni a fún un dípò ìbòrí. 16 Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni ò bá fara mọ́ àṣà yìí, a ò ní àṣà míì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ Ọlọ́run kò ní.

17 Àmọ́ bí mo ṣe ń fún yín ní àwọn ìtọ́ni yìí, mi ò gbóríyìn fún yín, nítorí kì í ṣe kí nǹkan lè dáa sí i lẹ ṣe ń pé jọ, kó lè burú sí i ni. 18 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá kóra jọ nínú ìjọ, ìpínyà máa ń wà láàárín yín; mo sì gbà á gbọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. 19 Ó dájú pé àwọn ẹ̀ya ìsìn tún máa wà láàárín yín,+ kí àwọn tí a tẹ́wọ́ gbà nínú yín lè fara hàn kedere.

20 Nígbà tí ẹ bá kóra jọ sí ibì kan, kì í wulẹ̀ ṣe láti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.+ 21 Torí nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹ́, kálukú á ti jẹ oúnjẹ alẹ́ tirẹ̀ ṣáájú, tó fi jẹ́ pé ebi á máa pa ẹnì kan, àmọ́ ọtí á máa pa ẹlòmíì. 22 Ṣé ẹ ò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ kí ẹ sì máa mu ni? Àbí ẹ̀ ń fojú pa ìjọ Ọlọ́run rẹ́, tí ẹ wá ń dójú ti àwọn tí kò ní nǹkan kan? Kí ni mo fẹ́ sọ fún yín? Ṣé kí n gbóríyìn fún yín ni? Lórí èyí, mi ò gbóríyìn fún yín.

23 Nítorí ọwọ́ Olúwa ni mo ti gba èyí tí mo fi lé yín lọ́wọ́, pé Jésù Olúwa mú búrẹ́dì ní alẹ́ ọjọ́+ tí a ó dalẹ̀ rẹ̀, 24 lẹ́yìn tó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi+ tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 25 Ó ṣe bákan náà ní ti ife náà,+ lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá.*+ Nígbàkigbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 26 Nítorí nígbàkigbà tí ẹ bá ń jẹ búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Olúwa, títí á fi dé.

27 Nítorí náà, ẹni tó bá jẹ búrẹ́dì náà tàbí tó mu ife Olúwa láìyẹ yóò jẹ̀bi nípa ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Kí èèyàn kọ́kọ́ dá ara rẹ̀ lójú lẹ́yìn tó bá ti yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa,+ ẹ̀yìn ìgbà yẹn nìkan ni kó jẹ nínú búrẹ́dì náà, kó sì mu nínú ife náà. 29 Nítorí ẹni tó bá ń jẹ, tó sì ń mu, láìfi òye mọ ohun tí ara náà jẹ́, ó ń jẹ, ó sì ń mu ìdájọ́ sórí ara rẹ̀. 30 Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ nínú yín fi jẹ́ aláìlera àti aláìsàn, tí àwọn díẹ̀ sì ń sùn nínú ikú.*+ 31 Àmọ́ tí a bá fi òye mọ ẹni tí àwa fúnra wa jẹ́, a ò ní dá wa lẹ́jọ́. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, Jèhófà* ló ń bá wa wí,+ kí a má bàa dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.+ 33 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá kóra jọ láti jẹ ẹ́, ẹ dúró de ara yín. 34 Tí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun nílé, kí ẹ má bàa kóra jọ fún ìdájọ́.+ Àmọ́ ní ti àwọn ọ̀ràn tó kù, màá bójú tó wọn nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín.

12 Ní ti àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí,+ ẹ̀yin ará, mi ò fẹ́ kí ẹ ṣaláìmọ̀ nípa rẹ̀. 2 Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ ṣì jẹ́ èèyàn orílẹ̀-èdè,* wọ́n ń nípa lórí yín, wọ́n ń kó yín ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà tí kò lè sọ̀rọ̀,+ ẹ sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́. 3 Ní báyìí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé kò sí ẹni tó bá ń fi ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ tó máa sọ pé: “Ẹni ègún ni Jésù!” kò sì sí ẹni tó lè sọ pé: “Jésù ni Olúwa!” àfi nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+

4 Oríṣiríṣi ẹ̀bùn ló wà, àmọ́ ẹ̀mí kan ló wà;+ 5 oríṣiríṣi iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló wà,+ síbẹ̀ Olúwa kan náà ló wà; 6 oríṣiríṣi iṣẹ́* ló wà, síbẹ̀ Ọlọ́run kan náà ló ń ṣe gbogbo iṣẹ́ náà nínú gbogbo èèyàn.+ 7 Àmọ́, à ń fi ẹ̀mí hàn nípasẹ̀ kálukú kí á lè ṣe àwọn míì láǹfààní.+ 8 A fún ẹnì kan ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n* nípasẹ̀ ẹ̀mí, a fún ẹlòmíì ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, 9 a fún òmíì ní ìgbàgbọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, a fún òmíì ní àwọn ẹ̀bùn ìwòsàn+ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, 10 síbẹ̀, a fún òmíì ní ẹ̀bùn láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ agbára,+ a fún òmíì ní ìsọtẹ́lẹ̀, a fún òmíì ní òye àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí,+ a fún òmíì ní ẹ̀bùn oríṣiríṣi èdè,*+ a sì fún òmíì ní ìtúmọ̀ àwọn èdè.+ 11 Àmọ́ gbogbo iṣẹ́ yìí ni ẹ̀mí kan náà yìí ń ṣe, ó ń pín ẹ̀bùn fún kálukú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́.

12 Nítorí bí ara ṣe jẹ́ ọ̀kan àmọ́ tó ní ẹ̀yà púpọ̀, tí gbogbo ẹ̀yà ara yẹn sì jẹ́ ara kan+ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Kristi. 13 Nítorí ipasẹ̀ ẹ̀mí kan ni a batisí gbogbo wa sínú ara kan, ì báà jẹ́ Júù tàbí Gíríìkì, ẹrú tàbí òmìnira, a sì mú kí gbogbo wa gba* ẹ̀mí kan.

14 Ní tòótọ́, kì í ṣe ẹ̀yà ara kan ṣoṣo ló dá di ara, ẹ̀yà ara púpọ̀ ni.+ 15 Tí ẹsẹ̀ bá sọ pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe apá kan ara,” ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara. 16 Tí etí bá sì sọ pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara. 17 Tí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, ibo ni agbára ìgbọ́ràn máa wà? Tí gbogbo rẹ̀ bá jẹ́ ìgbọ́ràn, ibo ni agbára ìgbóòórùn máa wà? 18 Àmọ́ ní báyìí, Ọlọ́run ti to ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bí ó ṣe fẹ́ sínú ara.

19 Tí gbogbo wọn bá jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà, ibo ni ara máa wà? 20 Àmọ́ ní báyìí bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà ara púpọ̀, ara kan ṣoṣo ni wọ́n. 21 Ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Mi ò nílò rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Mi ò nílò rẹ.” 22 Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀yà ara tó dà bíi pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára ṣe pàtàkì, 23 àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá ni à ń bọlá fún jù,+ nípa bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara wa tí kò jọni lójú ni à ń yẹ́ sí jù lọ, 24 nígbà tó jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà ara wa tó fani mọ́ra kò nílò ohunkóhun. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ṣètò ara, ó fún àwọn ẹ̀yà ara tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára ní ọlá tó pọ̀ jù, 25 kó má bàa sí ìpínyà kankan nínú ara, àmọ́ kí àwọn ẹ̀yà ara lè máa ṣìkẹ́ ara wọn.+ 26 Tí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara tó kù á bá a jìyà;+ tí a bá sì ṣe ẹ̀yà ara kan lógo, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù á bá a yọ̀.+

27 Ní báyìí, ẹ̀yin jẹ́ ara Kristi,+ kálukú yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara.+ 28 Ọlọ́run ti yan ẹnì kọ̀ọ̀kan sínú ìjọ: èkíní, àwọn àpọ́sítélì;+ èkejì, àwọn wòlíì;+ ẹ̀kẹta, àwọn olùkọ́;+ lẹ́yìn náà, àwọn iṣẹ́ agbára;+ lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀bùn ìwòsàn;+ àwọn iṣẹ́ ìrànwọ́; àwọn agbára láti máa darí+ àti oríṣiríṣi èdè.*+ 29 Kì í ṣe gbogbo wọn ni àpọ́sítélì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wòlíì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni olùkọ́, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára, àbí gbogbo wọn ni? 30 Kì í ṣe gbogbo wọn ló ní ẹ̀bùn ìwonisàn, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ló ń fi èdè fọ̀, àbí gbogbo wọn ni?+ Kì í ṣe gbogbo wọn ló jẹ́ olùtúmọ̀,* àbí gbogbo wọn ni?+ 31 Àmọ́ ẹ máa wá ẹ̀bùn tó tóbi jù.*+ Síbẹ̀, màá fi ọ̀nà tó ta yọ hàn yín.+

13 Tí mo bá ń fi èdè* èèyàn àti ti àwọn áńgẹ́lì sọ̀rọ̀ àmọ́ tí mi ò ní ìfẹ́, mo ti di abala idẹ tó ń dún tàbí síńbálì* olóhùn gooro. 2 Tí mo bá sì ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo lóye gbogbo àṣírí mímọ́ àti gbogbo ìmọ̀,+ tí mo ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè nípò pa dà,* àmọ́ tí mi ò ní ìfẹ́, mi ò já mọ́ nǹkan kan.*+ 3 Tí mo bá yọ̀ǹda gbogbo nǹkan tí mo ní láti bọ́ àwọn ẹlòmíì,+ tí mo sì fi ara mi lélẹ̀ kí n lè máa yangàn, àmọ́ tí mi ò ní ìfẹ́,+ kò ṣe mí láǹfààní kankan.

4 Ìfẹ́+ máa ń ní sùúrù*+ àti inú rere.+ Ìfẹ́ kì í jowú,+ kì í fọ́nnu, kì í gbéra ga,+ 5 kì í hùwà tí kò bójú mu,*+ kì í wá ire tirẹ̀ nìkan,+ kì í tètè bínú.+ Kì í di èèyàn sínú.*+ 6 Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo,+ àmọ́ ó máa ń yọ̀ lórí òtítọ́. 7 Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra,+ ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́,+ ó máa ń retí ohun gbogbo,+ ó máa ń fara da ohun gbogbo.+

8 Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé. Àmọ́ tí ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ bá wà, yóò dópin; tí àwọn ahọ́n àjèjì bá wà,* wọ́n á ṣíwọ́; tí ìmọ̀ bá wà, yóò dópin. 9 Nítorí a ní ìmọ̀ dé àyè kan,+ a sì ń sọ tẹ́lẹ̀ dé àyè kan, 10 àmọ́ nígbà tí èyí tó pé bá dé, èyí tó dé àyè kan yóò dópin. 11 Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ọmọdé, mò ń ronú bí ọmọdé, mo sì ń gbèrò bí ọmọdé; àmọ́ ní báyìí tí mo ti di ọkùnrin, mo ti fòpin sí àwọn ìwà ọmọdé. 12 Ní báyìí à ń ríran fírífírí* nínú dígí onírin, àmọ́ nígbà yẹn yóò jẹ́ kedere ní ojúkojú. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, mo ní ìmọ̀ dé àyè kan, àmọ́ nígbà yẹn màá ní ìmọ̀ tó péye,* bí Ọlọ́run ṣe mọ̀ mí lọ́nà tó péye. 13 Tóò, àwọn mẹ́ta tó ṣì wà nìyí: ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́; àmọ́ èyí tó tóbi jù lọ nínú wọn ni ìfẹ́.+

14 Ẹ máa lépa ìfẹ́, síbẹ̀ ẹ máa wá* àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí, àmọ́ ohun tó sàn jù ni pé kí ẹ máa sọ tẹ́lẹ̀.+ 2 Nítorí kì í ṣe èèyàn ni ẹni tó ń fi èdè fọ̀* ń bá sọ̀rọ̀, Ọlọ́run ni, torí kò sẹ́ni tó ń fetí sílẹ̀,+ bó tilẹ̀ ń sọ àwọn àṣírí mímọ́  + nípasẹ̀ ẹ̀mí. 3 Síbẹ̀, ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ ń gbéni ró, ó ń fúnni ní ìṣírí, ó sì ń tuni nínú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 4 Ẹni tó ń fi èdè fọ̀* ń gbé ara rẹ̀ ró, àmọ́ ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ ń gbé ìjọ ró. 5 Ní báyìí, ó wù mí kí gbogbo yín máa fi èdè fọ̀,*+ àmọ́ kí ẹ máa sọ tẹ́lẹ̀ ló wù mí jù.+ Ní tòótọ́, ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ tóbi ju ẹni tó ń fi èdè fọ̀, àfi tó bá ń túmọ̀* rẹ̀, kó lè máa gbé ìjọ ró. 6 Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ẹ̀yin ará, tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín tí mo sì ń fi èdè fọ̀,* àǹfààní wo ni màá ṣe yín láìjẹ́ pé mo bá yín sọ̀rọ̀ bóyá pẹ̀lú ìfihàn+ tàbí pẹ̀lú ìmọ̀+ tàbí pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tàbí pẹ̀lú ẹ̀kọ́?

7 Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí pẹ̀lú àwọn ohun aláìlẹ́mìí tó ń mú ìró jáde, ì báà jẹ́ fèrè tàbí háàpù. Tí àyè ò bá sí láàárín ìró wọn, báwo la ṣe máa mọ ohun tí wọ́n ń fi fèrè tàbí háàpù sọ? 8 Nítorí tí kàkàkí kò bá dún ketekete, ta ló máa gbára dì fún ogun? 9 Lọ́nà kan náà, láìjẹ́ pé ẹ fi ahọ́n yín sọ ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti lóye, báwo ni ẹnì kan ṣe máa mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ? Ní tòótọ́, ẹ̀ẹ́ kàn máa sọ̀rọ̀ sínú afẹ́fẹ́ ni. 10 Oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ló wà nínú ayé, síbẹ̀, kò sí èyí tí kò ní ìtúmọ̀. 11 Nítorí tí ọ̀rọ̀ náà ò bá yé mi, màá di àjèjì sí ẹni tó ń sọ̀rọ̀, ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà á sì di àjèjì sí mi. 12 Bó ṣe rí fún ẹ̀yin náà nìyẹn, torí pé ẹ̀ ń fẹ́ ẹ̀bùn ẹ̀mí lójú méjèèjì, ẹ máa wá ọ̀nà láti ní ẹ̀bùn púpọ̀ tó máa gbé ìjọ ró.+

13 Nítorí náà, kí ẹni tó ń fi èdè fọ̀* máa gbàdúrà kí ó lè ṣe ìtúmọ̀.*+ 14 Torí tí mo bá ń fi èdè* àjèjì gbàdúrà, ẹ̀bùn ẹ̀mí tí mo ní ló ń gbàdúrà, àmọ́ èrò inú mi ò ṣiṣẹ́. 15 Kí wá ni ṣíṣe? Màá fi ẹ̀bùn ẹ̀mí gbàdúrà, àmọ́ màá tún fi èrò inú mi gbàdúrà. Màá fi ẹ̀bùn ẹ̀mí kọrin ìyìn, àmọ́ màá tún fi èrò inú mi kọrin ìyìn. 16 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, tí o bá fi ẹ̀bùn ẹ̀mí mú ìyìn wá, báwo ni ẹni tí kò lóye tó wà láàárín yín ṣe máa ṣe “Àmín” sí ìdúpẹ́ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ò ń sọ? 17 Lóòótọ́, ò ń dúpẹ́ lọ́nà tó dáa, àmọ́ kò gbé ẹnì kejì rẹ ró. 18 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé mò ń sọ ọ̀pọ̀ èdè* ju gbogbo yín lọ. 19 Àmọ́ nínú ìjọ, ó yá mi lára kí n fi èrò inú* mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún, kí n lè kọ́* àwọn míì, ju pé kí n sọ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọ̀rọ̀ ní èdè* àjèjì.+

20 Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe di ọmọ kékeré nínú òye,+ àmọ́ ẹ di ọmọ kékeré ní ti ìwà burúkú;+ ẹ sì dàgbà di géńdé nínú òye.+ 21 Ó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin pé: “‘Màá bá àwọn èèyàn yìí sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ahọ́n àwọn àjèjì àti nípasẹ̀ ètè àwọn àjèjì, síbẹ̀ náà, wọn ò ní fetí sí mi,’ ni Jèhófà* wí.”+ 22 Nítorí náà, àwọn ahọ́n àjèjì kì í ṣe àmì fún àwọn onígbàgbọ́, àwọn aláìgbàgbọ́ ló wà fún,+ nígbà tó jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ kò wà fún àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn onígbàgbọ́ ló wà fún. 23 Nítorí náà, tí gbogbo ìjọ bá kóra jọ síbì kan, tí gbogbo wọn sì ń fi èdè fọ̀,* àmọ́ tí àwọn tí kò lóye tàbí àwọn aláìgbàgbọ́ wọlé wá, ṣé wọn ò ní sọ pé orí yín ti dà rú? 24 Àmọ́ tí gbogbo yín bá ń sọ tẹ́lẹ̀, tí aláìgbàgbọ́ tàbí ẹni tí kò mọ méjì sì wọlé wá, gbogbo ọ̀rọ̀ yín á bá a wí, á sì mú kó yẹ ara rẹ̀ wò fínnífínní. 25 Àwọn àṣírí tó wà lọ́kàn rẹ̀ á wá hàn síta, débi pé á dojú bolẹ̀, á sì jọ́sìn Ọlọ́run, á sọ pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín lóòótọ́.”+

26 Kí wá ni ṣíṣe, ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ bá kóra jọ, ẹnì kan ní sáàmù, ẹlòmíì ní ẹ̀kọ́, ẹlòmíì ní ìfihàn, ẹlòmíì ní èdè* àjèjì, ẹlòmíì sì ní ìtúmọ̀.+ Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ láti gbéni ró. 27 Tí ẹnì kan bá ń fi èdè fọ̀,* kí ó fi mọ sí méjì tàbí ó pọ̀ jù, mẹ́ta, kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ ní ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn, kí ẹnì kan sì máa ṣe ìtúmọ̀.*+ 28 Àmọ́ tí kò bá sí olùtúmọ̀,* kí ó dákẹ́ nínú ìjọ, kí ó sì máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀. 29 Kí wòlíì+ méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, kí àwọn tó kù sì fi òye mọ ìtúmọ̀. 30 Àmọ́ tí ẹlòmíì bá rí ìfihàn nígbà tó wà ní ìjókòó, kí ẹni àkọ́kọ́ tó ń sọ̀rọ̀ dákẹ́. 31 Torí náà, gbogbo àwọn tó ń sọ tẹ́lẹ̀ á máa sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn, kí gbogbo yín lè kẹ́kọ̀ọ́, kí ẹ sì gba ìṣírí.+ 32 Kí àwọn wòlíì máa kápá ẹ̀bùn ẹ̀mí tí àwọn wòlíì ní. 33 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.+

Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú gbogbo ìjọ àwọn ẹni mímọ́, 34 kí àwọn obìnrin máa dákẹ́ nínú ìjọ, nítorí a kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n wà ní ìtẹríba,+ gẹ́gẹ́ bí Òfin ṣe sọ. 35 Tí wọ́n bá fẹ́ mọ nǹkan kan, kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn nílé, nítorí ohun ìtìjú ni kí obìnrin máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.

36 Ṣé ọ̀dọ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wá ni àbí ọ̀dọ̀ yín nìkan ni ó dé?

37 Tí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ wòlíì tàbí pé òun ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, kí ó gbà pé àwọn ohun tí mò ń kọ sí yín jẹ́ àṣẹ Olúwa. 38 Àmọ́ tí ẹnì kan ò bá kà á sí, a ò ní ka òun náà sí.* 39 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa wá ọ̀nà láti sọ tẹ́lẹ̀,+ síbẹ̀ náà, ẹ má ka fífi èdè fọ̀*+ léèwọ̀. 40 Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.*+

15 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mò ń rán yín létí ìhìn rere tí mo kéde fún yín,+ èyí tí ẹ gbà, tí ẹ ò sì yà kúrò nínú rẹ̀. 2 Ipasẹ̀ rẹ̀ ni ẹ tún máa fi rí ìgbàlà, tí ẹ bá di ìhìn rere tí mo kéde fún yín mú ṣinṣin, àfi tó bá jẹ́ pé lásán lẹ di onígbàgbọ́.

3 Nítorí lára àwọn ohun tí mo kọ́kọ́ fi lé yín lọ́wọ́ ni ohun tí èmi náà gbà, pé Kristi kú nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ;+ 4 àti pé a sin ín,+ bẹ́ẹ̀ ni, pé a jí i dìde+ ní ọjọ́ kẹta+ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ;+ 5 àti pé ó fara han Kéfà,*+ lẹ́yìn náà, àwọn Méjìlá náà.+ 6 Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo,+ púpọ̀ nínú wọn ṣì wà pẹ̀lú wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú. 7 Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jémíìsì,+ lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì.+ 8 Àmọ́ ní paríparí rẹ̀, ó fara han èmi náà+ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.

9 Nítorí èmi ló kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì, mi ò sì yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì, torí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.+ 10 Àmọ́ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ lórí mi kò já sí asán, àmọ́ mo ṣiṣẹ́ ju gbogbo wọn lọ; síbẹ̀ kì í ṣe èmi, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tó wà pẹ̀lú mi ni. 11 Torí náà, ì báà jẹ́ èmi tàbí àwọn, bí a ṣe ń wàásù nìyí, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ ṣe gbà gbọ́.

12 Ní báyìí, tí a bá ń wàásù pé a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú,+ kí nìdí tí àwọn kan láàárín yín fi ń sọ pé kò sí àjíǹde àwọn òkú? 13 Tó bá jẹ́ òótọ́ ni pé kò sí àjíǹde àwọn òkú, á jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde. 14 Àmọ́ tí a ò bá tíì gbé Kristi dìde, ó dájú pé asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín. 15 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á mú wa ní ẹlẹ́rìí èké sí Ọlọ́run,+ torí a ti jẹ́rìí èké pé Ọlọ́run gbé Kristi dìde,+ ẹni tí kò gbé dìde tó bá jẹ́ pé a ò ní gbé àwọn òkú dìde lóòótọ́. 16 Nítorí tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde, á jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde. 17 Láfikún sí i, bí a ò bá tíì gbé Kristi dìde, ìgbàgbọ́ yín kò wúlò; ẹ ṣì wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.+ 18 Bákan náà, àwọn tó ti sun oorun ikú nínú Kristi ti ṣègbé.+ 19 Tó bá jẹ́ pé inú ìgbésí ayé yìí nìkan la ti ní ìrètí nínú Kristi, àwa ló yẹ kí wọ́n káàánú jù lọ nínú gbogbo èèyàn.

20 Àmọ́ ní báyìí, a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú, àkọ́so nínú àwọn tó ti sùn nínú ikú.+ 21 Nítorí bí ikú ṣe wá nípasẹ̀ ẹnì kan,+ àjíǹde òkú náà wá nípasẹ̀ ẹnì kan.+ 22 Nítorí bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú nínú Ádámù,+ bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.+ 23 Àmọ́ kálukú wà ní àyè rẹ̀: Kristi àkọ́so,+ lẹ́yìn náà àwọn tó jẹ́ ti Kristi nígbà tó bá wà níhìn-ín.+ 24 Ẹ̀yìn ìyẹn ni òpin, nígbà tó bá fi Ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, lẹ́yìn tó ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo àṣẹ àti agbára di asán.+ 25 Torí ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọba tí á máa ṣàkóso títí Ọlọ́run á fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 26 Ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn ni a ó sọ di asán.+ 27 Nítorí Ọlọ́run “fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”+ Àmọ́ nígbà tí a sọ pé ‘a ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,’+ ó ṣe kedere pé Ẹni tó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ kò sí lára wọn.+ 28 Àmọ́ nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, ìgbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ á fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,+ kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún kálukú.+

29 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ni àwọn tí à ń batisí kí wọ́n lè jẹ́ òkú máa ṣe?+ Tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde rárá, kí nìdí tí a fi ń batisí wọn kí wọ́n lè jíǹde? 30 Kí nìdí tí a fi ń wà nínú ewu ní wákàtí-wákàtí?*+ 31 Ẹ̀yin ará, ojoojúmọ́ ni mò ń dojú kọ ikú. Èyí dájú bí ayọ̀ tí mo ní lórí yín ṣe dájú, èyí tí mo ní nínú Kristi Jésù Olúwa wa. 32 Tó bá jẹ́ pé bíi tàwọn yòókù,* mo ti bá àwọn ẹranko jà ní Éfésù,+ àǹfààní wo ló máa ṣe mí? Tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde, “ẹ jẹ́ ká máa jẹ, ká sì máa mu, torí ọ̀la la máa kú.”+ 33 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere* jẹ́.+ 34 Ẹ jẹ́ kí orí yín pé lọ́nà òdodo, ẹ má sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà, nítorí àwọn kan ò ní ìmọ̀ Ọlọ́run. Mò ń sọ̀rọ̀ kí ojú lè tì yín.

35 Síbẹ̀, ẹnì kan á sọ pé: “Báwo ni àwọn òkú ṣe máa jíǹde? Bẹ́ẹ̀ ni, irú ara wo ni wọ́n ń gbé bọ̀?”+ 36 Ìwọ aláìnírònú! Tí ohun tí o gbìn ò bá kọ́kọ́ kú, ṣé ó lè hù* ni? 37 Ní ti ohun tí o gbìn, kì í ṣe ara tó máa dàgbà lo gbìn, hóró kan péré ni, ì báà jẹ́ ti àlìkámà* tàbí ti irúgbìn míì; 38 àmọ́ Ọlọ́run ń fún un ní ara bí ó ṣe wù ú, ó sì ń fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ní ara tirẹ̀. 39 Gbogbo ẹran ara kì í ṣe oríṣi kan náà, ti aráyé wà, ti ẹran ọ̀sìn wà, ti àwọn ẹyẹ wà, ti ẹja sì wà. 40 Àwọn ohun tó wà ní ọ̀run ní ara tiwọn,+ àwọn tó wà ní ayé sì ní tiwọn;+ ògo àwọn ohun tó wà ní ọ̀run jẹ́ oríṣi kan, ti àwọn tó wà ní ayé sì jẹ́ oríṣi míì. 41 Ògo oòrùn jẹ́ oríṣi kan, ògo òṣùpá jẹ́ oríṣi míì,+ ògo àwọn ìràwọ̀ sì jẹ́ oríṣi míì; kódà, ògo ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra.

42 Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí pẹ̀lú àjíǹde àwọn òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a gbé e dìde ní àìdíbàjẹ́.+ 43 A gbìn ín ní àbùkù; a gbé e dìde ní ògo.+ A gbìn ín ní àìlera; a gbé e dìde ní agbára.+ 44 A gbìn ín ní ara ìyára; a gbé e dìde ní ara tẹ̀mí. Bí ara ìyára bá wà, ti ẹ̀mí náà wà. 45 Ìdí nìyẹn tó fi wà lákọsílẹ̀ pé: “Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè.”*+ Ádámù ìkẹyìn di ẹ̀mí tó ń fúnni ní ìyè.+ 46 Síbẹ̀, èyí tó jẹ́ ti ẹ̀mí kọ́ ni àkọ́kọ́. Èyí tó jẹ́ ti ara ni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà ni èyí tó jẹ́ ti ẹ̀mí. 47 Ọkùnrin àkọ́kọ́ wá láti ayé, erùpẹ̀ sì ni a fi dá a;+ ọkùnrin kejì wá láti ọ̀run.+ 48 Bí ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá ṣe rí ni àwọn tí a fi erùpẹ̀ dá náà rí; bí ẹni ti ọ̀run ṣe rí ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ọ̀run náà rí.+ 49 Bí a ṣe gbé àwòrán ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá wọ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni a máa gbé àwòrán ẹni ti ọ̀run wọ̀.+

50 Àmọ́ mo sọ fún yín, ẹ̀yin ará, pé ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kì í jogún àìdíbàjẹ́. 51 Ẹ wò ó! Àṣírí mímọ́ ni mò ń sọ fún yín: Kì í ṣe gbogbo wa ló máa sùn nínú ikú, àmọ́ a máa yí gbogbo wa pa dà,+ 52 ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn. Nítorí kàkàkí máa dún,+ a máa gbé àwọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́, a sì máa yí wa pa dà. 53 Nítorí èyí tó lè bà jẹ́ gbọ́dọ̀ gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀,+ èyí tó lè kú sì gbọ́dọ̀ gbé àìkú wọ̀.+ 54 Àmọ́ nígbà tí èyí tó lè bà jẹ́ bá gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, tí èyí tó lè kú sì gbé àìkú wọ̀, ìgbà náà ni ọ̀rọ̀ tó ti wà lákọsílẹ̀ máa ṣẹ pé: “A ti gbé ikú mì títí láé.”+ 55 “Ikú, ìṣẹ́gun rẹ dà? Ikú, oró rẹ dà?”+ 56 Ẹ̀ṣẹ̀ ni oró tó ń mú ikú wá,+ inú Òfin sì ni agbára ẹ̀ṣẹ̀ ti ń wá.*+ 57 Àmọ́ ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, nítorí ó ń ṣẹ́gun fún wa nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi!+

58 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ dúró gbọn-in,+ ẹ má yẹsẹ̀,* kí ẹ máa ní ohun púpọ̀ láti ṣe+ nínú iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, kí ẹ sì mọ̀ pé làálàá yín kò ní já sí asán+ nínú Olúwa.

16 Ní ti àwọn ohun tí ẹ fẹ́ kó jọ fún àwọn ẹni mímọ́,+ ẹ lè tẹ̀ lé ìlànà tí mo fún àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà. 2 Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí kálukú yín ya ohun kan sọ́tọ̀ bí agbára rẹ̀ bá ṣe tó, kó má bàa sí pé ẹ̀ ń kó nǹkan jọ nígbà tí mo bá dé. 3 Àmọ́ nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, màá ní kí àwọn ọkùnrin tí ẹ fọwọ́ sí nínú àwọn lẹ́tà yín  + kó ẹ̀bùn àtọkànwá yín lọ sí Jerúsálẹ́mù. 4 Àmọ́, tí mo bá rí i pé ó yẹ kí èmi náà lọ síbẹ̀, wọ́n á bá mi lọ.

5 Ṣùgbọ́n màá wá sọ́dọ̀ yín tí mo bá ti kọjá ní Makedóníà, torí mo máa gba Makedóníà kọjá;+ 6 ó sì ṣeé ṣe kí n dúró tàbí kí n tiẹ̀ lo ìgbà òtútù pẹ̀lú yín, kí ẹ lè sìn mí dé ọ̀nà ibi tí mo bá ń lọ. 7 Torí mi ò kàn fẹ́ rí yín fẹ́rẹ́ tí mo bá ń kọjá, nítorí mo ní in lọ́kàn láti lo ìgbà díẹ̀ lọ́dọ̀ yín,+ tí Jèhófà* bá yọ̀ǹda. 8 Àmọ́ màá wà ní Éfésù+ títí di ìgbà Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì, 9 nítorí ilẹ̀kùn ńlá ti ṣí sílẹ̀ fún mi láti ṣe iṣẹ́ púpọ̀,+ àmọ́ ọ̀pọ̀ alátakò ló wà.

10 Tóò, tí Tímótì+ bá dé, ẹ rí i pé kò sí ohun kankan tó ń bà á lẹ́rù láàárín yín, nítorí iṣẹ́ Jèhófà* ló ń ṣe,+ bí èmi náà ti ń ṣe. 11 Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fojú kéré rẹ̀. Ẹ yọ̀ǹda rẹ̀ kó máa lọ ní àlàáfíà, kó lè wá sọ́dọ̀ mi, torí mò ń dúró dè é pẹ̀lú àwọn ará.

12 Ní ti Àpólò+ arákùnrin wa, mo pàrọwà fún un gidigidi láti tẹ̀ lé àwọn ará wá sọ́dọ̀ yín. Àmọ́ kò tíì fẹ́ wá báyìí, ó máa wá nígbà tí àyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.

13 Ẹ wà lójúfò,+ ẹ dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,+ ẹ ṣe bí ọkùnrin,*+ ẹ di alágbára.+ 14 Ẹ máa fi ìfẹ́ ṣe gbogbo ohun tí ẹ bá ń ṣe.+

15 Ní báyìí, mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ará: Ẹ mọ̀ pé agbo ilé Sítéfánásì ni àkọ́so Ákáyà àti pé wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́. 16 Kí ẹ̀yin náà máa tẹrí ba fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ àti fún gbogbo àwọn tó ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ kára.+ 17 Inú mi dùn pé Sítéfánásì+ àti Fọ́túnátù pẹ̀lú Ákáíkọ́sì wà níbí, nítorí wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ bá máa ṣe ká ní ẹ wà níbí. 18 Wọ́n ti mú ìtura bá ẹ̀mí mi àti tiyín. Nítorí náà, ẹ máa ka irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sí.

19 Àwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà kí yín. Ákúílà àti Pírísíkà pẹ̀lú ìjọ tó wà ní ilé wọn+ kí yín tayọ̀tayọ̀ nínú Olúwa. 20 Gbogbo àwọn ará kí yín. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

21 Ìkíni èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ.

22 Tí ẹnikẹ́ni kò bá nífẹ̀ẹ́ Olúwa, kí ó di ẹni ègún. Ìwọ Olúwa wa, máa bọ̀! 23 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa wà pẹ̀lú yín. 24 Kí ìfẹ́ mi wà pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jésù.

Tàbí “àjọpín.”

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “tì sí ẹ̀gbẹ́ kan.”

Ìyẹn, ọ̀jáfáfá nínú Òfin.

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “lójú èèyàn.”

Tàbí “nínú ìdílé tó lórúkọ.”

Ní Grk., “ẹlẹ́ran ara.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kan Olúwa ológo mọ́ òpó igi.”

Ní Grk., “àfi ẹ̀mí.”

Tàbí “pa àwọn ọ̀rọ̀ tẹ̀mí pọ̀ mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí.”

Tàbí “kì í gba.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “èrò kan náà ni ẹni tó ń gbìn àti ẹni tó ń bomi rin ní.”

Tàbí “ọlọ́gbọ́n olùdarí àwọn iṣẹ́.”

Ní Grk., “fara hàn kedere.”

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A5.

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Tàbí “ọmọ abẹ́.”

Tàbí “kóòtù.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ṣàpèjúwe.”

Ní Grk.,“a wà ní ìhòòhò.”

Tàbí “gbá wa káàkiri.”

Ní Grk., “a wá ojú rere.”

Tàbí “ìdọ̀tí.”

Tàbí “olùkọ́.”

Ní Grk., “àwọn ọ̀nà mi.”

Wo Àfikún A5.

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ń gbé pẹ̀lú.”

Tàbí “dídarapọ̀.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

Tàbí “dídarapọ̀.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

Tàbí “ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú.”

Tàbí “tàn yín jẹ.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

Tàbí “àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀.” Ní Grk., “àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin sùn.”

Tàbí “ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú.”

Tàbí “làyè gbà.”

Tàbí “mú mi wá sábẹ́ àṣẹ.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú.

Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, por·neiʹa tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “pínyà.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “aláìkọlà.”

Tàbí “Ìkọlà.”

Tàbí “àìkọlà.”

Tàbí “àwọn tí kò tíì lọ́kọ tàbí láya.”

Ní Grk., “ìran.”

Ní Grk., “dẹ okùn mú yín.”

Tàbí “hùwà tí kò yẹ sí ipò wúńdíá òun.”

Ó ń tọ́ka sí ìgbà tí ìfẹ́ ìbálòpọ̀ máa ń lágbára lára ọ̀dọ́.

Tàbí “láti pa ipò wúńdíá rẹ̀ mọ́.”

Tàbí “tó bá fi ipò wúńdíá rẹ̀ fúnni nínú ìgbéyàwó.”

Ní Grk., “sọ ẹ̀rí ọkàn wọn tí kò lágbára di ẹlẹ́gbin.”

Ní Grk, “àṣẹ.”

Tàbí “mú arábìnrin tó jẹ́ ìyàwó.”

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Ní Grk., “àṣẹ.”

Tàbí “ẹ̀tọ́.”

Tàbí “Gbogbo eléré ìdárayá.”

Tàbí “fìyà jẹ ara mi; bá ara mi wí lọ́nà líle.”

Tàbí “ẹni ìtanù.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí “sì ni.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “làyè gbà.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “tí a dá lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ mi.”

Ó ṣe kedere pé ikú nípa tẹ̀mí ló ń tọ́ka sí.

Wo Àfikún A5.

Ìyẹn, aláìgbàgbọ́.

Tàbí “ọ̀nà ìṣiṣẹ́.”

Tàbí “A fi iṣẹ́ ọgbọ́n rán ẹnì kan.”

Ní Grk., “ahọ́n.”

Ní Grk., “mu.”

Ní Grk., “ahọ́n.”

Tàbí “atúmọ̀ èdè.”

Tàbí “fi ìtara wá ẹ̀bùn tó tóbi jù.”

Ní Grk., “ahọ́n.”

Tàbí “aro.”

Tàbí “kúrò lọ sí ibòmíì.”

Tàbí “wúlò.”

Tàbí “ìpamọ́ra.”

Tàbí “ṣe ọ̀yájú.”

Tàbí “Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”

Ìyẹn, kéèyàn máa fi iṣẹ́ ìyanu sọ àwọn èdè míì.

Tàbí “bàìbàì.”

Tàbí “tó kún rẹ́rẹ́.”

Tàbí “fi ìtara wá.”

Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Tàbí “ṣe ògbufọ̀.”

Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Tàbí “ògbufọ̀.”

Tàbí “ahọ́n.”

Ní Grk., “fi ọ̀pọ̀ ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Tàbí “òye.”

Tàbí “fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́.”

Tàbí “ahọ́n.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Tàbí “ahọ́n.”

Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Tàbí “ògbufọ̀.”

Tàbí “atúmọ̀ èdè.”

Tàbí kó jẹ́, “tí ẹnì kan bá jẹ́ aláìmọ̀kan, yóò máa jẹ́ aláìmọ̀kan nìṣó.”

Ní Grk., “fífi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Tàbí “nípa ètò.”

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Tàbí “ní gbogbo ìgbà?”

Tàbí kó jẹ́, “lójú ti èèyàn.”

Tàbí “ìwà ọmọlúwàbí.”

Tàbí “yè.”

Tàbí “wíìtì.”

Tàbí “alààyè ọkàn.”

Tàbí “Òfin ló ń fún ẹ̀ṣẹ̀ ní agbára.”

Tàbí “ẹ di aláìṣeéṣínípò.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ẹ jẹ́ onígboyà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́