ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 2/8 ojú ìwé 24-28
  • Ìpèníjà àti Ìbùkún Tó Wà Nínú Títọ́ Ọmọkùnrin Méje

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpèníjà àti Ìbùkún Tó Wà Nínú Títọ́ Ọmọkùnrin Méje
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọwọ́ Mi Dí Gan-an!
  • Fífi Ìlànà Bíbélì Kọ́ Àwọn Ọmọkùnrin Wa
  • Iṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
  • Kíkọ́gbọ́n Nínú Ọ̀ràn Kéèkì
  • A Ń Gbádùn Ayé Wa
  • Ojú Tí Àwọn Ọmọkùnrin Náà Fi Wo Ẹ̀kọ́ Ìbáwí
  • A Ní Àwọn Ìfàsẹ́yìn
  • Ìyípadà Ńlá Nínú Ìgbésí Ayé Wa
  • Mo Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà Nítorí Àwọn Ọmọkùnrin Mi Márààrún
    Jí!—1999
  • Àwọn Irúgbìn Tó Sèso Lẹ́yìn Ọ̀pọ̀ Ọdún
    Jí!—1999
  • Àwọn Òbí Wa Kọ́ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Kí Nìdí Táwọn Ọkùnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 2/8 ojú ìwé 24-28

Ìpèníjà àti Ìbùkún Tó Wà Nínú Títọ́ Ọmọkùnrin Méje

Bí Bert àti Margaret Dickman ṣe sọ ọ́

Ọdún 1927 ni wọ́n bí mi, ní Omaha, Nebraska, U.S.A., mo sì dàgbà ní Gúúsù Dakota. Mo rántí ìgbà tí mo wà lọ́mọdé ní àwọn ọdún líle koko ti Ìjórẹ̀yìn Ọrọ̀ Ajé Lọ́nà Gígọntiọ (1929 sí 1942). Ìyá mi máa ń se irú ọbẹ̀ kan tó ń pè ní ọbẹ̀ pàdémi-nígùn-únpá. Yóò da ọ̀rá díẹ̀ sínú abọ́ ìdín-ǹkan, yóò bu omi díẹ̀ sí i, a óò wá máa fi búrẹ́dì wa kàn án. Nǹkan kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ ìdílé lákòókò yẹn.

ÀWỌN ará ilé mi kò lẹ́mìí ìsìn—wọ́n rí i pé ìwà àgàbàgebè pọ̀ nínú ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì tó wà ládùúgbò. Ní tèmi, ìgbòkègbodò mi lọ́dún méjì tí mo lò nínú iṣẹ́ ológun nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ló ń darí ìrònú mi. Ìgbà yẹn ni mo káṣà mímutí àti títa tẹ́tẹ́.

Nígbà ìsinmi kan, mo lọ ságbo ijó kan ládùúgbò níbi tí mo ti pàdé Margaret Schlaht, ọmọbìnrin kan tó ti inú ìdílé aládàlù Germany òun Ukraine wá. Àwa méjèèjì nífẹ̀ẹ́ ara wa, lẹ́yìn tí a sí fẹ́ra sọ́nà fún oṣù mẹ́ta, a ṣègbéyàwó ní 1946. Láàárín ọdún mẹ́jọ, a ti bí ọmọkùnrin méje, ìṣòro ọmọ títọ́ sì fojú wa rí bótò.

Ní 1951, jàǹbá bíburújáì kan ṣe mí ní ìsọ̀ pákó tó fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kí ìdajì apá òsì mi kọṣẹ́ nísàlẹ̀. Ọdún méjì ni mo fi wà ní ilé ìwòsàn tí mo ń gbàtọ́jú gbígbé ẹran ara àti egungun mi sípò. Láàárín àkókò náà, Margaret ló ń bójú tó àwọn ọmọkùnrin márùn-ún. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò, ó la àkókò líle koko náà já. Nígbà tí mo wà ní ilé ìwòsàn, mo ní àkókò tí ó pọ̀ tó láti fi ronú nípa ète ìgbésí ayé. Mo gbìyànjú láti ka Bíbélì àmọ́ n kò fi bẹ́ẹ̀ lóye rẹ̀.

Láìpẹ́ lẹ́yìn tí mo kúrò ní ilé ìwòsàn, a kó lọ sí Opportunity, ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ Washington, èmi àti ẹ̀gbọ́n ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ kọ́lékọ́lé. Nísinsìnyí, n óò jẹ́ kí Margaret sọ tirẹ̀ nínú ìtàn náà.

Ọwọ́ Mi Dí Gan-an!

Àgbègbè oko kan tí a dáko ọkà sí, tí a lóko ìfúnwàrà kékeré kan sí, tí a sì ti ń ṣe omi èso àti ewébẹ̀ sínú agolo, ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Mo jẹ́ kí iṣẹ́ ṣíṣe mọ́ mi lára, èyí tó múra mi sílẹ̀ fún àwọn ìpèníjà ìgbésí ayé, tí yóò pọ̀ níwájú. Àkókò Ìjórẹ̀yìn Ọrọ̀ Ajé náà kò fi bẹ́ẹ̀ le fún wa bó ti le fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, nítorí pé ó kéré tán oúnjẹ kì í wọ́n wa.

Àwọn òbí mi kò ráyè ti ẹ̀sìn, àmọ́ èmi máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbà tó yá, èmi àti Bert ṣègbéyàwó nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún. A kò lọ ṣe é ní ṣọ́ọ̀ṣì—a wúlẹ̀ ṣe ayẹyẹ kékeré kan ní pálọ̀ àwọn òbí mi ni, àlùfáà ìjọ Congregational ló darí ètò náà. Láàárín ọdún bí mélòó kan, mo ti bí ọmọkùnrin méje—Richard, Dan, Doug, Gary, Michael, Ken àti Scott, tí mo bí kẹ́yìn ní 1954. Wọ́n pọ̀ díẹ̀!

Lẹ́yìn tí a kó lọ sí Opportunity, obìnrin kan wá sí ilé wa láti bá wa sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Mo bi í léèrè bóyá ó nígbàgbọ́ nínú ọ̀run àpáàdì, ẹ̀kọ́ kan tó máa ń já mi láyà gan-an. Ọkàn mi balẹ̀ bó ṣe ń ṣàlàyé pé ọ̀run àpáàdì kì í ṣe ẹ̀kọ́ tó ti inú Bíbélì wá àti pé ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn kò sí nínú Bíbélì! Ó ti pẹ́ tí ẹ̀rù ti máa ń bà mí tí mo sì ń bẹ̀rù àtikú, n kò sì lè mú ọ̀ràn ọ̀run àpáàdì bára dọ́gba pẹ̀lú Ọlọ́run ìfẹ́. Mo pinnu pé n kò ní kọ́ àwọn ọmọ mi ní irú ẹ̀kọ́ èké yẹn.

Ní 1955, mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ.”a Bí ẹ ti lè ronú pé yóò ṣẹlẹ̀, ìgbà yẹn gan-an ni oníwàásù ọmọ ìjọ Pentecostal yẹn wá lọ́kàn ìfẹ́ sí mi, ó fẹ́ gbà mí lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Ó ṣe àṣìṣe ńlá kan—ó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù nípa ọ̀run àpáàdì fún mi! Ó tilẹ̀ rán àwọn obìnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ Pentecostal rẹ̀ wá gbà mí níyànjú láti máà jẹ́ kí Àwọn Ẹlẹ́rìí bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́.

Láàárín àkókò kan náà, Bert ń fetí sí ẹ̀kọ́ tí mo ń kọ́ nínú Bíbélì láti inú pálọ̀. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí ka Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, àwọn nǹkan túbọ̀ wá ń yé e. Òru ló máa ń ṣíwọ́ níbi iṣẹ́. Màá ti sùn kó tó dé. Mo yọ́ kẹ́lẹ́ lọ sí ìsàlẹ̀ lóru ọjọ́ kan, mo sì bá a níbi tó ti ń jí àwọn ìwé mi kà! Mo fẹ̀sọ̀ tẹlẹ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ padà sórí bẹ́ẹ̀dì, inú mi dùn pé òun fúnra rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, òun pẹ̀lú kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sì ṣèrìbọmi bí Ẹlẹ́rìí ní 1956.

Níwọ̀n bí a ti bí ọmọkùnrin méje láàárín ọdún mẹ́jọ, mo wá rí i pé ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ ilé tí ó kan fífún wọn lóúnjẹ àti pípèsè aṣọ fún wọn àti gbígbìyànjú láti jẹ́ kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní lójoojúmọ́ jẹ́ ìpèníjà. Àwọn ọmọkùnrin wa kọ́ bí àwọn náà ṣe lè ṣe ipa tiwọn nínú iṣẹ́ ilé. Mo sábà máa ń sọ pé n kò ní ẹ̀rọ ìfabọ́ kan—méje tán ni mo ní! Ńṣe ni wọ́n máa ń pín iṣẹ́ pàtàkì yìí ṣe. Àmọ́, Bert ń ṣèrànwọ́ gan-an. Ó ń rí i dájú pé ẹ̀kọ́ ilé àti ìtọ́ni kò wọ́n wọn nígbàkigbà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì jẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pòórá. Àwọn ọmọkùnrin náà bọ̀wọ̀ fún bàbá wọn, àmọ́ kì í ṣe pé ẹ̀rù rẹ̀ máa ń bà wọ́n. Bert kò pa ojúṣe rẹ̀ tì láti kọ́ àwọn ọmọkùnrin wa nípa ohun tí ó máa ń pè ní “àwọn ẹyẹ àti oyin” tí inú wọn máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá rántí rẹ̀.

Richard, ọmọkùnrin wa tó dàgbà jù, yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti lọ sìn ní orílé-iṣẹ́ Watch Tower Society ní Brooklyn, New York, ní 1966. Ìdánwò ńlá ló jẹ́ fún mi nígbà tí èyí àkọ́bí ń fi ilé sílẹ̀. Àga tó máa ń ṣófo nídìí tábìlì ìjẹun lójoojúmọ́ máa ń mú kí ọ̀ràn náà máa dùn mí dé ọkàn. Ṣùgbọ́n inú mi dùn pé ó ń ní ìrírí rere, ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ tó dára.

N óò jẹ́ kí Bert máa bá ọ̀rọ̀ náà lọ.

Fífi Ìlànà Bíbélì Kọ́ Àwọn Ọmọkùnrin Wa

Èmi àti Margaret ṣèrìbọmi ní àpéjọpọ̀ kan ní Spokane, Washington. Nígbà yẹn, a ní ìpèníjà fífi ìlànà Bíbélì kọ́ àwọn ọmọkùnrin wa—ohun tí o lè pè ní àṣà àtijọ́. N kò gba irọ́ pípa tàbí gbígbé ìgbésí ayé méjì rárá, àwọn ọmọkùnrin wa náà sì mọ̀. A kọ́ wọn pé ohun tó dára jù lọ ló tọ́ sí Jèhófà.

Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé àwọn lè fọkàn tán mi nítorí a ní àjọṣe tímọ́tímọ́, a sì ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan papọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé, a gbádùn lílọ sí etíkun, jíjáde fàájì lọ sí ìtòsí àwọn òkè ńlá, àti eré bọ́ọ̀lù jíjù. A ní àwọn ẹran, a sì dáko, gbogbo àwọn ọmọkùnrin náà ni wọ́n sì ń ṣe ipa tiwọn nínú ohunkóhun tí a bá ní í ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ́ bí a ti ń ṣiṣẹ́ tí a sì ń ṣeré. A gbìyànjú láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú àwọn ìgbòkègbodò wa.

Iṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Ní ti ọ̀ràn tẹ̀mí, gbogbo wa la ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, a sì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa déédéé. Ní 1957, a lọ sí àpéjọpọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Seattle, Washington. Nígbà tí ìpàdé náà ń lọ lọ́wọ́, wọ́n ké sí àwọn ìdílé láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí láti wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Ìdílé wa ronú pé ó dára, a sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò láti kó lọ. Lákọ̀ọ́kọ́, a lọ sí Missouri ní 1958, lẹ́yìn náà, a lọ sí Mississippi ní 1959.

Ní 1958, a dáwọ́ lé iṣẹ́ ńlá àkọ́kọ́ tí a ṣe nínú iṣẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Mo ṣe ilé àfọkọ̀fà kan, tí a ń fi DeSoto, ògbólógbòó ọkọ̀ kan tí ń gbé ẹni mẹ́ta, tí wọ́n ṣe ní 1947, fà. Àwa mẹ́sẹ̀ẹ̀sàn-án wọ ọkọ̀ yẹn lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé kan ní New York lọ́dún yẹn. A lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan lójú ọ̀nà, a ń pàgọ́ lọ́nà láti Spokane, ní Etíkun Ìwọ̀ Oòrùn, dé New York—tí ó jìn ju ẹgbàajì ó lé igba [4,200] kìlómítà lọ! Àwọn ọmọkùnrin wa máa ń láyọ̀ tí wọ́n bá rántí ìrìn àjò yẹn bí ó ṣe jẹ́ àkókò pàtàkì àti amóríyá gan-an.

Kíkọ́gbọ́n Nínú Ọ̀ràn Kéèkì

Ní àpéjọpọ̀ àgbáyé yẹn, a gba ẹ̀dà tiwa lára ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada.b Ìwé yẹn àti Bíbélì wá di lájorí ìwé tí a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àtikékeré ni gbogbo àwọn ọmọdékùnrin wa ti kọ́ bí a ti ń kàwé. Marge máa ń lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin wa tí wọ́n bá ti dé láti ilé ẹ̀kọ́, ó máa ń fetí sí bí wọ́n ṣe ń ka Bíbélì. A kò jẹ́ kí tẹlifíṣọ̀n gbà wọ́n lọ́kàn.

Ẹ̀kọ́ ilé àti ọ̀wọ̀ kò wọ́n nínú ìdílé wa. Nígbà kan, Margaret ṣe kéèkì ńlá kan—ọ̀kan lára àwọn ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe jù. Kárọ́ọ̀tì wà lára oúnjẹ ọjọ́ yẹn. A sábà máa ń gba àwọn ọmọkùnrin wa níyànjú pé kí wọ́n máa jẹ ewébẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ díẹ̀. Doug kò fẹ́ràn kárọ́ọ̀tì. A sọ fún un pé bí kò bá jẹ kárọ́ọ̀tì, kò ní jẹ kéèkì lọ́jọ́ yẹn. Síbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ rẹ̀ tán. Margaret sọ pé, “Bí o kò bá jẹ àwọn kárọ́ọ̀tì yẹn, ajá ló máa jẹ kéèkì ẹ.” N kò rò pé Doug gba ìyá rẹ̀ gbọ́ àyàfi ìgbà tó rí i tí Blackie ń jẹ kéèkì aládùn rẹ̀! Ó kọ́ ẹ̀kọ́ kan nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, àwọn ọmọkùnrin wa yòókù sì kọ́gbọ́n nínú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí òbí, a kì í yí ohun tí a bá sọ padà.

A Ń Gbádùn Ayé Wa

Ohun tó ń ṣamọ̀nà èmi àti Margaret ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tó wà nínú Mátíù 6:33 pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” Gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, a gbìyànjú láti fi ire Ìjọba náà sí ipò kìíní. Gbogbo wa gbádùn jíjùmọ̀ lọ wàásù, àwọn ọmọkùnrin wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sì máa ń bá mi lọ láti ilé dé ilé. Olúkúlùkù wọn ló ní àpò ìkówèésí, Bíbélì, àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tirẹ̀. A máa ń yìn wọ́n fún ìtẹ̀síwájú èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe. Margaret sábà máa ń gbá wọn mọ́ra dáadáa. Láìṣe àní-àní, a máa ń fi ìfẹ́ni hàn sí wọn déédéé. Ìgbà gbogbo ni a máa ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin náà—a ń gbádùn ayé wa!

Bí àwọn ọmọkùnrin náà ṣe ń dàgbà, wọ́n ní àwọn ẹrù iṣẹ́ bí lílọ mú àwọn ènìyàn wá sí ìpàdé, ṣíṣí Gbọ̀ngàn Ìjọba, àti ṣíṣèrànwọ́ nínú àwọn iṣẹ́ mìíràn. Wọ́n kọ́ bí wọ́n ṣe ní láti mọyì Gbọ̀ngàn Ìjọba bí ibi ìjọsìn wọn, inú wọn sì ń dùn láti bójú tó o.

A rọ̀ wọ́n láti máa dáhùn ní àwọn ìpàdé Kristẹni. Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí kò gùn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, níbi tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀díẹ̀ nípa bí wọn ó ṣe di olùbánisọ̀rọ̀. Michael, ọmọkùnrin wa karùn-ún, kì í sábà fẹ́ láti sọ̀rọ̀ ní gbangba, ó sì máa ń ní ìṣòro lórí pèpéle. Tó bá ṣiṣẹ́ dé àárín, yóò bẹ̀rẹ̀ sí da omijé lójú nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì tó bá a, níwọ̀n bí kò ti lè parí rẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, ó borí ìyẹn, nísinsìnyí tó ti di baálé ilé, ó ń sìn bí alábòójútó arìnrìn-àjò, ó ń bẹ àwọn ìjọ wò, ó sì ń sọ àwíyé ní ọ̀pọ̀ ìgbà láàárín ọ̀sẹ̀. Ìyípadà gbáà lèyí jẹ́!

Ojú Tí Àwọn Ọmọkùnrin Náà Fi Wo Ẹ̀kọ́ Ìbáwí

Akọ̀ròyìn Jí! kàn sí Michael láti gbọ́ èrò rẹ̀ lórí títọ́ ọ lọ́nà ti àtijọ́. “A ka Dádì sí ẹni tí ń báni wí kí a lè ní láárí. Mo rántí pé nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba, mo ń bá ilé iṣẹ́ rédíò kan ṣiṣẹ́. Mo fẹ́ láti ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan kí n baà lè tún máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún. Ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Ford Mustang rẹ̀, tí a lè ká ìbòrí rẹ̀ kúrò, tó ní ilẹ̀kùn méjì lọ̀ mí, ó jẹ́ ọkọ̀ aláfẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń gbé kiri. Ó wù mí gan-an, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé kì í ṣe ọkọ̀ tó wúlò fún gbígbé àwọn ènìyàn kiri nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Mo lọ bá Dádì pẹ̀lú ìbẹ̀rù lọ́kàn. Nígbà tí mo sọ fún un nípa ọkọ̀ náà, ó sọ pé, ‘Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.’ Mo mọ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí! Ó sọ èrò ọkàn rẹ̀ fún mi, ó ṣàlàyé àǹfààní tó wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó wúlò. Nítorí náà mo ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ onílẹ́kùn mẹ́rin, lẹ́yìn tí mo sì ti lò ó fún ọ̀kẹ́ mẹ́jọ [160,000] kìlómítà níbi iṣẹ́ ìwàásù àyànfúnni mi, nǹkan tí mo lè sọ ni pé, ‘Ọ̀rọ̀ Dádì mà tún já sí òótọ́.’

“Ìrírí tó gbádùn mọ́ni ni bí a ṣe ń kó káàkiri nígbà tí a wà lọ́mọdé jẹ́—láti Washington sí Missouri àti lẹ́yìn náà sí Mississippi. A gbádùn rẹ̀. Kódà bí ó ti jẹ́ pé jálẹ̀ ọdún kan, àwa mẹ́sàn-án la ń gbé inú ilé àfọkọ̀fà tí ó jẹ́ mítà méjì ààbọ̀ níbùú àti mítà mọ́kànlá lóròó, ìgbádùn ni gbogbo rẹ̀ jẹ́, ó sì kọ́ wa láti wà létòlétò, kí a sì gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú ara wa, kódà nínú ilé tó há. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìta la ti máa ń ṣeré lọ́pọ̀ ìgbà.

“Ohun mìíràn tí mo rántí, tí mo sì nífẹ̀ẹ́ ni bí Dádì ṣe máa ń darí [ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́] pẹ̀lú wa. Ní 1966, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn alàgbà ní Kingdom Farm, ní Gúúsù Lansing, New York, ó sì rí i pé ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń ṣe ìwádìí kí wọ́n lè sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ [Ìwé Mímọ́] ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ó mú ohun kan náà wọ inú ìgbòkègbodò ìdílé wa. Wọ́n ń yanṣẹ́ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwa méjèèje láti sọ̀rọ̀ lórí ohun tí a bá ṣèwádìí lé nípa rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a máa ń ráhùn, àmọ́ ó kọ́ wa bí a ṣe ń ṣe ìwádìí, kí a sì ṣàlàyé ara wa. Irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ kì í yá gbàgbé.

“Àwọn ìfara-ẹni rúbọ tí Mọ́mì àti Dádì ṣe nítorí wa wọ̀ mí lọ́kàn. Nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n mi méjèèjì Richard àti Dan ì bá máa pawó wálé fún ìdílé wa, àwọn òbí wa rọ̀ wọ́n láti lọ sí Brooklyn, New York, láti lọ sìn bí olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ní orílé-iṣẹ́ àgbáyé Watch Tower Society. Àwọn òbí wa tún fowó pamọ́ kí àwa márùn-ún lè fi wọkọ̀ òfuurufú lọ sí New York láti lọ fojú ara wa rí bí orílẹ̀-iṣẹ́ náà ṣe rí. Ìyẹn nípa lórí mi gan-an. Ó mú kí ìmọrírì wa fún ètò-àjọ Jèhófà pọ̀ sí i.

“Wàyí o, ẹ jẹ́ kí n fún Dádì láyè láti máa bá ọ̀rọ̀ náà lọ.”

A Ní Àwọn Ìfàsẹ́yìn

Bíi ti ìdílé èyíkéyìí mìíràn, a ní àwọn ìṣòro àti ìfàsẹ́yìn tiwa. Bí àwọn ọmọkùnrin wa ti ń dàgbà tó láti ní àfẹ́sọ́nà, mo ní láti fún wọn ní ìṣítí nípa yíyára kówọnú ìgbéyàwó pẹ̀lú ọmọge tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí. A tún rí i dájú pé wọn kì í dá nìkan wà pa pọ̀. A fẹ́ kí wọ́n ní ìrírí ìgbésí ayé díẹ̀ kí wọ́n tó yan aya tí wọn óò bá gbé ní gbogbo àkókò tí wọn ó fi wà láàyè. Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń sunkún, wọ́n sì máa ń rẹ̀wẹ̀sì ní àwọn ìgbà kan, àmọ́, níkẹyìn wọ́n wá rí ọgbọ́n tó wà nínú àmọ̀ràn Bíbélì—ní pàtàkì láti gbéyàwó “nínú Olúwa.” A yìn wọ́n fún ìwà ọlọgbọ́n tí wọ́n hù.—1 Kọ́ríńtì 7:39.

Scott, àbíkẹ́yìn wa pa wá lẹ́kùn díẹ̀. Ó juwọ́ sílẹ̀ fún ẹgbẹ́ búburú níbi iṣẹ́ rẹ̀. Níkẹyìn, a yọ ọ́ nínú ìjọ. Àjálù ńlá nìyẹn jẹ́ fún gbogbo wa, ṣùgbọ́n a kò janpata pẹ̀lú ìdájọ́ tí àwọn alàgbà ṣe. Ìrírí líle koko ló kọ́ Scott lọ́gbọ́n pé sísin Jèhófà ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ.

A kò fìgbà kan jáwọ́ nínú pé kí ó padà sínú ìjọ. Ó dùn mọ́ni nínú pé lẹ́yìn ọdún márùn-ún, a gbà á padà sínú ìjọ. Ó ronú nípa àwọn ọjọ́ tó ti kọjá, ó sọ pé, “Ohun kan tó ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n yọ mí lẹ́gbẹ́ ni pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìdílé láàlà gan-an, ìgbà gbogbo ni mo mọ̀ pé ìdílé mi nífẹ̀ẹ́ mi.” Scott ń tẹ̀ síwájú, ó sì ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn.

Ó ṣeniláàánú pé a yọ méjì lára àwọn ọmọ-ọmọ wa lẹ́gbẹ́ ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ṣùgbọ́n a ní ìtùnú pé ẹ̀kọ́ tó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá lè mú ìyípadà sí rere wá.

Ìyípadà Ńlá Nínú Ìgbésí Ayé Wa

Níkẹyìn, ní 1978, gbogbo àwọn ọmọkùnrin wa ti fi ilé sílẹ̀. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, mo ti ní ìrírí nínú iṣẹ́ ẹ̀rọ amúlémóoru, ìfẹ́lọfẹ́bọ̀ afẹ́fẹ́, àti amúlétutù. Ní 1980, èmi àti Margaret gba ìkésíni àgbàyanu kan pé kí a wá fi oṣù mẹ́sàn-án sìn ní orílé-isẹ́ Watch Tower Society ní Brooklyn. Lẹ́yìn ọdún méjìdínlógún, a ṣì wà níhìn-ín!

A ti rí ìbùkún gbà lọ́pọ̀ yanturu. Kò fìgbà gbogbo rọrùn fún wa láti tọ́ àwọn ọmọkùnrin wa dàgbà lọ́nà ti àtijọ́, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì, àmọ́, ó ti ṣèrànwọ́ nínú ọ̀ràn tiwa. Bí nǹkan ṣe rí nínú ìdílé wa báyìí ni pé márùn-ún lára àwọn ọmọkùnrin wa ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ, ọ̀kan sì jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. A ní ogún ọmọ-ọmọ àti àtọmọdọ́mọ mẹ́rin—ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ló wà nínú òtítọ́, wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run.

A ti rí bí ọ̀rọ̀ onísáàmù ti jẹ́ òtítọ́ pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà; èso ikùn jẹ́ èrè. Bí àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà èwe rí.”—Sáàmù 127:3, 4.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe ní 1946; tí a kò tẹ̀ mọ́ báyìí.

b Tí Watchtower Bible and Tracts Society of New York, Inc., ṣe.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwa àti àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ìyàwó wọn (apá ọ̀tún) àti àwọn ọmọ-ọmọ (apá ọ̀tún lọ́hùn-ún) nígbà ayẹyẹ àádọ́ta ọdún ìgbéyàwó wa ní 1996

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́