ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 85-87
  • Ìwà Burúkú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwà Burúkú
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 85-87

Ìwà Burúkú

Àwọn ìwà wo ló yẹ kí Kristẹni yẹra fún?

Àgàbàgebè

Wo “Àgàbàgebè”

Agídí

Jer 13:10

Tún wo Jer 7:23-27; Sek 7:11, 12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 36:11-17—Ọba burúkú tó lágídí gan-an ni Sedekáyà, ó sì fi tiẹ̀ kó bá àwọn èèyàn ẹ̀

    • Iṣe 19:8, 9—Nígbà táwọn kan kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò ní gba ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tí Pọ́ọ̀lù ń sọ gbọ́, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn

Awuyewuye

Flp 2:3; Jem 3:14-16

Ìbẹ̀rù èèyàn

Sm 118:6; Owe 29:25; Mt 10:28

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Nọ 13:25-33—Torí pé ẹ̀rù ń ba àwọn amí mẹ́wàá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sọ̀rọ̀ tó mú kí ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù

    • Mt 26:69-75—Torí pé Pétérù ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ pé òun ò mọ Jésù rí

Ìbínú

Sm 37:8, 9; Owe 29:22; Kol 3:8

Tún wo Owe 14:17; 15:18

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 37:18, 19, 23, 24, 31-35—Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù kórìíra ẹ̀ débi pé wọ́n fìyà jẹ ẹ́, wọ́n tà á bí ẹrú, wọ́n sì ṣe ohun tó mú kí Jékọ́bù gbà pé Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ti kú

    • Jẹ 49:5-7—Jékọ́bù gégùn-ún fún Síméónì àti Léfì, torí pé ìbínú wọn ti le jù

    • 1Sa 20:30-34—Torí pé inú ń bí Ọba Sọ́ọ̀lù gan-an, ó fàbùkù kan Jónátánì ọmọ ẹ̀, ó sì fẹ́ pa á

    • 1Sa 25:14-17—Nábálì sọ̀rọ̀ àbùkù sáwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, díẹ̀ ló sì kù kí Dáfídì pa Nábálì àti gbogbo ọkùnrin tó wà nínú agbo ilé ẹ̀

Ìfẹ́ owó, ohun ìní

Mt 6:24; 1Ti 6:10; Heb 13:5

Tún wo 1Jo 2:15, 16

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Job 31:24-28—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni Jóòbù, ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ju ọrọ̀ lọ

    • Mk 10:17-27—Jésù sọ pé kí ọ̀dọ́kùnrin kan wá di ọmọ ẹ̀yìn òun, àmọ́ kò gbà torí pé ohun ìní ẹ̀ pọ̀

Ìfura burúkú àti àtakò

Job 1:9-11; 1Ti 6:4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 18:6-9; 20:30-34—Ọba Sọ́ọ̀lù rò pé Dáfídì fẹ́ gba ìjọba mọ́ òun lọ́wọ́, ó sì gbìyànjú láti kẹ̀yìn Jónátánì àti Dáfídì síra wọn

Ìgbéraga; ìfọ́nnu

Ga 5:26; Flp 2:3

Tún wo Owe 3:7; 26:12; Ro 12:16

Tún wo “Ìgbéraga”

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Sa 15:1-6—Ábúsálómù jẹ́ agbéraga, ó ń dọ́gbọ́n fa ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ra kí wọ́n lè fẹ́ràn ẹ̀ ju Ọba Dáfídì tó jẹ́ bàbá ẹ̀ lọ

    • Da 4:29-32—Jèhófà bá Ọba Nebukadinésárì wí torí pé ó jẹ́ agbéraga

Ìjà

Owe 26:20; 1Ti 3:2, 3; Tit 3:2

Tún wo Owe 15:18; 17:14; 27:15; Jem 3:17, 18

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 13:5-9—Ìjà ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tó ń da ẹran ọ̀sìn Ábúráhámù àti àwọn tó ń da ẹran ọ̀sìn Lọ́ọ̀tì, àmọ́ Ábúráhámù ṣe ohun tó mú kí àlàáfíà jọba

    • Ond 8:1-3—Àwọn ọkùnrin Éfúrémù fẹ́ bá Gídíónì jà, àmọ́ torí pé Gídíónì sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ara àwọn ọkùnrin náà balẹ̀

Ìkórìíra

Owe 10:12; Tit 3:3; 1Jo 4:20

Tún wo Nọ 35:19-21; Mt 5:43, 44

Ìkọjá Àyè

Wo “Ìkọjá Àyè”

Ìlara; ojúkòkòrò

Ro 13:9; 1Pe 2:1

Tún wo Ga 5:26; Tit 3:3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 26:12-15—Jèhófà bù kún Ísákì torí pé ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, àwọn Filísínì wá ń ṣe ìlára ẹ̀

    • 1Ọb 21:1-19—Torí pé Áhábù tó jẹ́ Ọba burúkú fẹ́ gba ọgbà àjàrà Nábótì, ó ní káwọn kan parọ́ mọ́ ọn, kí wọ́n sì pa á

Inú burúkú

1Sa 30:6; Ef 4:31; Kol 3:19

Tún wo Jem 3:14

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ọbd 10-14—Ọlọ́run fìyà jẹ àwọn ọmọ Édómù torí pé wọ́n hùwà ìkà sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá wọn

Ìwà Àìlọ́wọ̀

Wo “Ìwà Àìlọ́wọ̀”

Ìwà àìnírònú

Mk 7:21-23; Ef 5:17

Tún wo 1Pe 2:15

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 8:10-20—Lẹ́yìn tí Sámúẹ́lì sọ ohun tó fi hàn pé kò bọ́gbọ́n mu báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ní kó fún àwọn ní ọba, èsì tí wọ́n fún Sámúẹ́lì fi hàn pé aláìnírònú ni wọ́n

    • 1Sa 25:2-13, 34—Nígbà tí Nábálì yarí pé òun ò ní fún Dáfídì ní ohun tó yẹ kó fún un, díẹ̀ ló kù kó fi ìwà àìnírònú ẹ̀ kó bá ara ẹ̀ àti agbo ilé ẹ̀

Ìwà ọ̀dájú

Di 15:7, 8; Mt 19:8; 1Jo 3:17

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 42:21-24—Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù kábàámọ̀ ìwà ìkà tí wọ́n hù sí i

    • Mk 3:1-6—Ẹ̀dùn ọkàn bá Jésù gidigidi torí ìwà ọ̀dájú táwọn Farisí hù

Òdodo àṣelékè

Onw 7:16; Mt 7:1-5; Ro 14:4, 10-13

Tún wo Ais 65:5; Lk 6:37

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 12:1-7—Ohun tí Jésù sọ fún àwọn Farisí fi hàn pé òdodo àṣelékè lásán ni wọ́n ń ṣe

    • Lk 18:9-14—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run kì í fojú tó dáa wo àwọn olódodo àṣelékè

Ojo

2Ti 1:7; Ifi 21:8

Ojúkòkòrò

Wo “Ojúkòkòrò”

Owú

Wo “Owú”

Ọ̀lẹ

Owe 6:6-11; Onw 10:18; Ro 12:11

Tún wo Owe 10:26; 19:15; 26:13

Ọ̀tẹ̀

1Sa 15:23; Jud 4, 8, 10, 11

Tún wo Di 21:18-21; Sm 78:7, 8; Tit 1:10

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́