ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/01 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 31
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 12/01 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 10

Orin 205

13 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún olúkúlùkù níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò To the Ends of the Earth láti múra sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ December 24. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi (1) Ilé Ìṣọ́ December 15 lọni àti (2) bí a ṣe lè fi Jí! January 8 lọni.

12 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun.” Àsọyé. Ṣe ìfilọ̀ déètì tí ẹ ó ṣe àpéjọ àyíká tó ń bọ̀. Ó yẹ kí gbogbo ìjọ sapá lákànṣe láti ké sí àwọn tí wọ́n ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá. Fún àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi níṣìírí láti ronú jinlẹ̀ nípa fífàmì ìyàsímímọ́ wọn fún Jèhófà hàn ní àpéjọ àyíká tó ń bọ̀. Rọ gbogbo ìjọ láti wà níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

20 min: “Àwọn Ìbùkún Tó Ń Wá Látinú Fífi Ìmọrírì Hàn fún Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní sí Wa—Apá Kejì.”a Nígbà tí o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2 sí 6, ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìrírí afúnniníṣìírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà, nípa kíkọ lẹ́tà àti lórí tẹlifóònù. Ṣètò ṣáájú fún àṣefihàn kan tàbí méjì tí yóò fi àpẹẹrẹ bí ìrírí wọn ṣe wáyé hàn.

Orin 222 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 17

Orin 211

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Sọ àwọn ètò àkànṣe tó wà fún iṣẹ́ ìsìn pápá fún December 25 àti January 1.

22 min: “Fí Ọwọ́ Tó Tọ́ Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”b Fi àṣefihàn gidi kan kún un nípa bí a ṣe lè lo ìgbékalẹ̀ tó wà ní ìpínrọ̀ 4. Bákan náà, ṣàṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tó gbéṣẹ́, tí a ti lò ládùúgbò yín láti fi pèsè ìṣírí fún àwọn tí ìdààmú bá nítorí ipò tí ayé wà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ tàbí láti fi bá wọn dárò. O lè ní kí wọ́n sọ ìrírí kúkúrú kan. Sọ pé kí àwùjọ sọ ìdí tí wọ́n fi rò pé ìwàásù wọn á túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i bí wọ́n bá ń lo Bíbélì.

13 min: “Emi Kò Nífẹ̀ẹ́ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.” Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwùjọ, tí a gbé karí ìwé pẹlẹbẹ náà Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó lójú ewé 9 àti 10. Bí àwọn èèyàn bá ń lọ́ra láti fetí sílẹ̀ nítorí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí la lè sọ? Ṣètò ṣáájú pé kí àwọn akéde kan ṣàlàyé àwọn ìdáhùn tí a dábàá lọ́rọ̀ ara wọn.

Orin 225 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 24

Orin 218

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù January àti àwọn ìwé tí ìjọ bá ní. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣàṣefihàn méjì tó ṣe ṣókí nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni, kí ọ̀kan lo Ilé Ìṣọ́ January 1, kí èkejì sì lo Jí! January 8. Jẹ́ kí ọ̀dọ́ kan fi ọ̀kan nínú wọn lọni.

10 min: “Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2002.” Àsọyé tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí pé kí wọ́n máa sapá láti ṣe iṣẹ́ tí a bá yàn fún wọn.

25 min: “Jíjẹ́rìí—Títí Dé Òpin Ilẹ̀ Ayé.” Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwùjọ. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti ronú jinlẹ̀ lórí bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ sapá sí i láti wàásù fún àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ tàbí níbi tí wọ́n ti túbọ̀ ń fẹ́ ìrànwọ́. Tọ́ka sí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù July 2001, ní ojú ìwé 4. Ní oṣù February a ó ṣàyẹ̀wò fídíò Noah—He Walked With God. Ní àfidípò, sọ̀rọ̀ lórí “Àwọn Àpẹẹrẹ Rere—Ṣé O Ń Jàǹfààní Lára Wọn?” Alàgbà ni kí ó sọ àsọyé yìí tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 1, 2000, ojú ìwé 19 sí 21.

Orin 24 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 31

Orin 140

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù December sílẹ̀. Bí ìjọ yín yóò bá yí àkókò tí ẹ ń ṣe ìpàdé padà lọ́dún tuntun, fi pẹ̀lẹ́tù rọ gbogbo ìjọ pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé déédéé ní àwọn àkókò tí a yí wọn padà sí. Kí ẹ rí i dájú pé gbogbo àwọn olùfìfẹ́hàn àti àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ èyíkéyìí mọ̀ nípa ìyípadà náà.

15 min: Ẹ Máa Gba Ti Àwọn Alàgbà Rò Bí Ó Ti Yẹ. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjì tàbí mẹ́ta jíròrò Ilé Ìṣọ́ June 1, 1999, ojú ìwé 18 àti 19. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù iṣẹ́ tí àwọn alàgbà ń bójú tó, títí kan iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ojúṣe wọn nínú ìdílé, àti iṣẹ́ àyànfúnni wọn tó jẹ́ ti Ìjọba Ọlọ́run. Kí wọ́n ṣàyẹ̀wò bí gbogbo ìjọ ṣe lè fún àwọn alàgbà ní ìṣírí, kí wọ́n jẹ́ kí ẹrù tí wọ́n ń gbé fúyẹ́, kí wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọn. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà gbà pé àwọn alàgbà ń ṣiṣẹ́ tó níye lórí, nítorí náà wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí “ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ.”—1 Tẹs. 5:12, 13.

22 min: “Mú Agbára Ìmòye Rẹ Dàgbà.”c Alàgbà kan ṣe àgbéyẹ̀wò tó ń gbádùn mọ́ni lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tó kọjá.

Orin 195 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 7

Orin 20

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: Gbádùn Ayé Rẹ. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé jíròrò Ilé Ìṣọ́ August 15, 1998, ojú ìwé 8 àti 9. Bàbá náà fẹ́ kí ìdílé rẹ̀ ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ tí wọn kò ní kábàámọ̀. Wọ́n gbé àwọn ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yẹ̀ wò látinú àpilẹ̀kọ náà tí ó sọ bí wọ́n ṣe lè láyọ̀ ní ti gidi, ìyẹn nípasẹ̀ níní ìfòyemọ̀, fífi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì ṣáájú, àti gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa àwọn àtúnṣebọ̀sípò tí wọ́n lè ṣe lápapọ̀ bí ìdílé.

15 min: Pípe Àfiyèsí sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa. Àsọyé tí alàgbà kan sọ. Kíyè sí bí Gbọ̀ngàn Ìjọba wá ṣe rí. Àwọn ètò wo là ń ṣe fún ṣíṣe ìmọ́tótó gbogbo gbòò ṣáájú Ìṣe Ìrántí? Àwọn àtúnṣe wo ló pọn dandan láti ṣe ṣáájú ìgbà yẹn? Ṣàlàyé bí àwọn mẹ́ńbà ìjọ ṣe lè ṣèrànwọ́. Tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí a rí i pé ibi ìjọsìn wa ń gbé ẹwà àti iyì tí ó yẹ ilé Jèhófà yọ.—Sm. 84:1.

Orin 126 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́