ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Sunday, August 10

Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.—Òwe 17:17.

Nígbà tí ìyàn ńlá mú àwọn ará ní Jùdíà, àwọn ará tó wà ní ìjọ Áńtíókù ti Síríà gbọ́ nípa ìyàn náà. Torí náà, wọ́n “pinnu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbára kálukú wọn gbé, láti fi nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ará tó ń gbé ní Jùdíà.” (Ìṣe 11:​27-30) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi táwọn ará tí ìyàn náà mú ń gbé jìnnà gan-an, àwọn ará tó wà ní Áńtíókù pinnu pé àwọn gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́. (1 Jòh. 3:​17, 18) Àwa náà lè fàánú hàn sáwọn ará wa lónìí tá a bá gbọ́ pé àjálù ṣẹlẹ̀ sí wọn. Bá a ṣe lè fi hàn pé à ń káàánú àwọn ará wa ni pé tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí wọn, ká tètè béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà bóyá a lè yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Yàtọ̀ síyẹn, a lè fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé tàbí ká gbàdúrà fáwọn tí àjálù dé bá. Ó tún lè pọn dandan pé ká ran àwọn ará wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò. Torí náà, tí Jésù Kristi Ọba wa bá dé láti ṣèdájọ́ ayé burúkú yìí, ó máa rí i pé à ń fàánú hàn sáwọn èèyàn, á sì pè wá pé ká wá “jogún Ìjọba” náà.—Mát. 25:​34-40. w23.07 4 ¶9-10; 6 ¶12

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Monday, August 11

Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.—Fílí. 4:5.

Jésù máa ń fòye báni lò bíi ti Jèhófà. Jèhófà rán an wá sáyé kó lè wàásù fún “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.” Síbẹ̀, ó máa ń fòye báni lò bó ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn. Nígbà kan, obìnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀ ẹ́ pé kó wo ọmọbìnrin òun sàn torí pé ‘ẹ̀mí èṣù ń yọ ọ́ lẹ́nu gidigidi.’ Àánú obìnrin yẹn ṣe Jésù, ó ṣe ohun tó sọ, ó sì wo ọmọbìnrin ẹ̀ sàn. (Mát. 15:​21-28) Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ míì. Lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi . . . , èmi náà máa sẹ́ ẹ.” (Mát. 10:33) Àmọ́ nígbà tí Pétérù sẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣé ó pa á tì? Rárá. Jésù mọ̀ pé Pétérù kábàámọ̀ ohun tó ṣe, olóòótọ́ sì ni. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kó fi dá a lójú pé òun ti dárí jì í àti pé òun ṣì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Lúùkù 24:​33, 34) Jèhófà àti Jésù Kristi máa ń fòye báni lò. Àwa ńkọ́? Jèhófà fẹ́ káwa náà máa fòye báni lò. w23.07 21 ¶6-7

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, August 12

Ikú ò ní sí mọ́.—Ìfi. 21:4.

Kí la lè sọ fáwọn tí ò gbà pé Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé? Àkọ́kọ́, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ṣèlérí yẹn. Ìwé Ìfihàn sọ pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé: ‘Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’” Jèhófà ní ọgbọ́n àti agbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ohun tó sì fẹ́ ṣe nìyẹn. Ìkejì, ó dá Jèhófà lójú háún-háún pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ bíi pé ó ti ṣẹ. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni. . . . Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀!” Ìkẹta, tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ ohun kan, ó dájú pé ó máa parí ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà.” (Ìfi. 21:6) Torí náà, Jèhófà máa fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, kò sì lè dí òun lọ́wọ́ láti mú ìlérí òun ṣẹ. Torí náà, tẹ́nì kan bá sọ pé, “Àlá tí ò lè ṣẹ ni,” ka Ìfihàn 21:​5, 6 fún ẹni náà, kó o sì ṣàlàyé ẹ̀. O lè jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé Jèhófà ti fi dá wa lójú pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, òun sì ti fi òòtẹ̀ lù ú.—Àìsá. 65:16. w23.11 7 ¶18-19

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́