ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Monday, August 18

Nítorí ìlérí Ọlọ́run, . . . ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú kó di alágbára.—Róòmù 4:20.

Àwọn alàgbà wà lára àwọn tí Jèhófà ń lò láti fún wa lókun. (Àìsá. 32:​1, 2) Torí náà, tí nǹkan kan bá ń dà ẹ́ láàmú, sọ nǹkan náà fáwọn alàgbà. Tí wọ́n bá láwọn fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́, má kọ ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe fún ẹ. Ìdí sì ni pé Jèhófà lè lò wọ́n láti mú kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára. Àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé àwọn Kristẹni kan máa gbé ọ̀run títí láé, àwọn yòókù sì máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè máa ń jẹ́ ká nírètí. (Róòmù 4:​3, 18, 19) Ìrètí tá a ní yìí ń fún wa lókun ká lè fara da ìṣòro, ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì máa ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. (1 Tẹs. 1:3) Ìrètí yẹn kan náà ló fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lókun. Ó sọ pé wọ́n ‘há òun gádígádí, ọkàn òun dà rú, wọ́n ṣe inúnibíni sí òun, wọ́n sì gbé òun ṣánlẹ̀.’ Kódà, ẹ̀mí ẹ̀ máa ń wà nínú ewu. (2 Kọ́r. 4:​8-10) Pọ́ọ̀lù rí okun gbà torí pé ó tẹjú mọ́ ohun tó ń retí, ìyẹn sì jẹ́ kó fara da àwọn ìṣòro ẹ̀. (2 Kọ́r. 4:​16-18) Pọ́ọ̀lù tẹjú mọ́ èrè ọjọ́ iwájú tó ní láti gbé ọ̀run títí láé. Ó máa ń ronú nípa ìrètí yẹn, torí náà, ó ń di “ọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.” w23.10 15-16 ¶14-17

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, August 19

Jèhófà yóò fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní agbára. Jèhófà yóò fi àlàáfíà jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀.—Sm. 29:11.

Tó o bá ń gbàdúrà, wò ó bóyá àsìkò ti tó lójú Jèhófà láti dáhùn àdúrà ẹ. Ó lè máa ṣe wá bíi pé kí Jèhófà dáhùn àdúrà wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà mọ àsìkò tó dáa jù láti dáhùn àdúrà wa. (Héb. 4:16) Tá ò bá tètè rí ìdáhùn àdúrà wa, a lè rò pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé kò tíì tó àsìkò lójú ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin ọ̀dọ́ kan lè bẹ Jèhófà pé kó wo òun sàn. Àmọ́ Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sọ pé Jèhófà wò ó sàn lọ́nà ìyanu ni, Sátánì lè sọ pé torí pé Jèhófà wò ó sàn ló ṣe ń sin Jèhófà. (Jóòbù 1:​9-11; 2:4) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti mọ ìgbà tó máa mú gbogbo àìsàn kúrò pátápátá. (Àìsá. 33:24; Ìfi. 21:​3, 4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a ò lè retí pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa wò wá sàn lọ́nà ìyanu. Torí náà, arákùnrin yẹn lè bẹ Jèhófà pé kó fún òun lókun, kó sì jẹ́ kọ́kàn òun balẹ̀ kóun lè máa fara da àìsàn náà, kóun sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. w23.11 23 ¶13

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Wednesday, August 20

Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa, kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.—Sm. 103:10.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúsìn ṣe àṣìṣe ńlá, síbẹ̀ kò jẹ́ kó sú òun láti máa sin Jèhófà. Ó lo àǹfààní tó ní láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un, ìyẹn ni pé kó gbéjà ko àwọn Filísínì. (Oníd. 16:​28-30) Sámúsìn bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun ‘gbẹ̀san lára àwọn Filísínì.’ Ọlọ́run tòótọ́ dáhùn àdúrà Sámúsìn, ó sì fún un lágbára lọ́nà ìyanu. Àwọn Filísínì tí Sámúsìn pa lọ́tẹ̀ yìí pọ̀ gan-an ju àwọn tó pa tẹ́lẹ̀ lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúsìn jìyà àbájáde àṣìṣe tó ṣe, kò ṣíwọ́ láti máa sin Jèhófà. Torí náà tá a bá ṣàṣìṣe, tí wọ́n sì bá wa wí tàbí tá a pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa sin Jèhófà nìṣó. Máa rántí pé Jèhófà kì í jẹ́ kọ́rọ̀ wa sú òun. (Sm. 103:​8, 9) Torí náà, tá a bá tiẹ̀ ṣe àwọn àṣìṣe kan, Jèhófà ṣì lè lò wá bó ṣe lo Sámúsìn. w23.09 6 ¶15-16

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́