ORIN 22
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!
- 1. Jèhófà, o ti wà tipẹ́, - Ìwọ yóò wà láéláé. - O ti fàṣẹ yan Ọmọ rẹ; - O gbé e gorí ìtẹ́. - Ìjọba náà ti wà lọ́run; - Yóò ṣàkóso ayé láìpẹ́. - (ÈGBÈ) - Ìgbàlà wa ti dé! - Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀. - Jèhófà, a bẹ̀ ọ́, - “Jọ̀wọ́, jẹ́ kó dé, jẹ́ kó dé!” 
- 2. Àwọn áńgẹ́lì ńyọ̀ lọ́run, - Wọ́n bú sórin ayọ̀. - Torí a ti l’Éṣù jáde - Kúrò ní àárín wọn. - Ìjọba náà ti wà lọ́run; - Yóò ṣàkóso ayé láìpẹ́. - (ÈGBÈ) - Ìgbàlà wa ti dé! - Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀. - Jèhófà, a bẹ̀ ọ́, - “Jọ̀wọ́, jẹ́ kó dé, jẹ́ kó dé!” 
- 3. Sátánì yóò pa run láìpẹ́; - Ìdáǹdè wa dé tán. - À ń róhun tí ayé kò rí, - Bí ìpọ́njú tiẹ̀ pọ̀. - Ìjọba náà ti wà lọ́run; - Yóò ṣàkóso ayé láìpẹ́. - (ÈGBÈ) - Ìgbàlà wa ti dé! - Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀. - Jèhófà, a bẹ̀ ọ́, - “Jọ̀wọ́, jẹ́ kó dé, jẹ́ kó dé!” 
(Tún wo Dán. 2:34, 35; 2 Kọ́r. 4:18.)