ORIN 148
Jèhófà Ń Ṣe Ọ̀nà Àsálà
- 1. Jèhófà, Ọlọ́run alààyè mà ni ọ́; - À ńríṣẹ́ ọwọ́ rẹ - láyé àti lọ́run. - Kò sí ọlọ́run tó lè bá ọ dọ́gba, - kò ní sí. - Ọ̀tá wa yóò ṣègbé. - (ÈGBÈ) - Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́. - Àwa èèyàn rẹ̀ yóò jẹ́rìí ságbára rẹ̀. - Ká nígbàgbọ́ àti ìgboyà, - ká máa wàásù - Nípa Ọlọ́run ìgbàlà wa, - ká sì máa yìnín. 
- 2. Ẹ̀mí mi fẹ́ bọ́, mo ké pè ọ́ Jèhófà, - “Jọ̀ọ́ fún mi lágbára, - mo nílò okun rẹ.” - O sì wá gbọ́ àdúrà àtọkànwá - tí mo gbà, - O sì wá kó mi yọ. - (ÈGBÈ) - Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́. - Àwa èèyàn rẹ̀ yóò jẹ́rìí ságbára rẹ̀. - Ká nígbàgbọ́ àti ìgboyà, - ká máa wàásù - Nípa Ọlọ́run ìgbàlà wa, - ká sì máa yìnín. 
- 3. Ohùn rẹ yóò dún bí àrá - látọ̀run wá. - Ọ̀tá rẹ yóò páyà; - àwa yóò kún fáyọ̀. - Alèwílèṣe ni ọ́, Ọlọ́run wa. - Aó sì ríi - Bí wàá ṣe gbà wá là. - (ÈGBÈ) - Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà fólóòótọ́. - Àwa èèyàn rẹ̀ yóò jẹ́rìí ságbára rẹ̀. - Ká nígbàgbọ́ àti ìgboyà, - ká máa wàásù - Nípa Ọlọ́run ìgbàlà wa, - ká sì máa yìnín. 
(Tún wo Sm. 18:1, 2; 144:1, 2.)