ORIN 26
Ẹ Ti Ṣe É fún Mi
- 1. Àwọn arákùnrin Kristi tó wà láyé - ni àwọn àgùntàn mìíràn ńbá ṣiṣẹ́. - Gbogbo ìsapá wọn - láti ràn wọ́n lọ́wọ́ - Ni Jésù sọ pé wọ́n máa gba èrè rẹ̀. - (ÈGBÈ) - “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú. - Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.” 
- 2. “Nígbà tébi ń pa mí, tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí, - gbogbo ohun tí mo nílò lẹ pèsè.” - Wọ́n béèrè pé: “Ìgbà wo - la ṣe nǹkan wọ̀nyí?” - Ọba náà máa dá wọn lóhùn, yóò sọ pé: - (ÈGBÈ) - “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú. - Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.” 
- 3. “Ẹ ti dúró tì mí, iṣẹ́ rere lẹ̀ ń ṣe. - Ẹ̀ ń wàásù pẹ̀l’áwọn arákùnrin mi.” - Ọba máa sọ fáwọn - tó wà lọ́tùn-ún rẹ̀ pé: - “Ẹ di pípé, kí ẹ sì jogún ayé.” - (ÈGBÈ) - “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú. - Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.” 
(Tún wo Òwe 19:17; Mát. 10:40-42; 2 Tím. 1:16, 17.)