15 Mo wà pẹ̀lú rẹ, màá dáàbò bò ọ́ ní gbogbo ibi tí o bá lọ, màá sì mú ọ pa dà sí ilẹ̀ yìí.+ Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí màá fi ṣe ohun tí mo ṣèlérí fún ọ.”+
42 Ká ní Ọlọ́run bàbá mi,+ Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ẹni tí Ísákì ń bẹ̀rù*+ kò tì mí lẹ́yìn ni, ọwọ́ òfo lò bá ní kí n kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ọlọ́run ti rí ìyà tó ń jẹ mí àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ìdí nìyẹn tó fi bá ọ wí lóru àná.”+