Ẹ́kísódù 29:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 “Kí o mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+ Ẹ́kísódù 29:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 kí o mú òróró àfiyanni,+ kí o sì dà á sí i lórí láti fòróró yàn án.+ Ẹ́kísódù 30:30 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 30 Kí o fi òróró yan Áárónì+ àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ kí o sì sọ wọ́n di mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi.+ Ẹ́kísódù 40:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Kí o wọ àwọn aṣọ mímọ́ náà fún Áárónì,+ kí o fòróró yàn án,+ kí o sì sọ ọ́ di mímọ́, yóò sì di àlùfáà mi. Léfítíkù 21:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 “‘Ẹni tó jẹ́ àlùfáà àgbà nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n da òróró àfiyanni+ sí lórí, tí wọ́n sì ti fi iṣẹ́ lé lọ́wọ́* kó lè wọ aṣọ àlùfáà,+ kò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ̀ sílẹ̀ láìtọ́jú tàbí kó ya aṣọ rẹ̀.+ Sáàmù 133:2 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 Ó dà bí òróró dáradára tí a dà sí orí,+Tó ń ṣàn sára irùngbọ̀n,Irùngbọ̀n Áárónì,+Tó sì ń ṣàn sí ọrùn aṣọ rẹ̀.
13 Kí o wọ àwọn aṣọ mímọ́ náà fún Áárónì,+ kí o fòróró yàn án,+ kí o sì sọ ọ́ di mímọ́, yóò sì di àlùfáà mi.
10 “‘Ẹni tó jẹ́ àlùfáà àgbà nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n da òróró àfiyanni+ sí lórí, tí wọ́n sì ti fi iṣẹ́ lé lọ́wọ́* kó lè wọ aṣọ àlùfáà,+ kò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ̀ sílẹ̀ láìtọ́jú tàbí kó ya aṣọ rẹ̀.+
2 Ó dà bí òróró dáradára tí a dà sí orí,+Tó ń ṣàn sára irùngbọ̀n,Irùngbọ̀n Áárónì,+Tó sì ń ṣàn sí ọrùn aṣọ rẹ̀.