-
2 Kíróníkà 5:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ akọrin+ tí wọ́n jẹ́ ti Ásáfù,+ ti Hémánì,+ ti Jédútúnì + àti ti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn ló wọ aṣọ àtàtà, síńbálì* wà lọ́wọ́ wọn àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù; wọ́n dúró sí apá ìlà oòrùn pẹpẹ, àwọn pẹ̀lú ọgọ́fà (120) àlùfáà tó ń fun kàkàkí.+
-
-
2 Kíróníkà 7:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àwọn àlùfáà dúró sí ibi iṣẹ́ wọn, bí àwọn ọmọ Léfì náà ṣe dúró pẹ̀lú ohun èlò tí wọ́n fi ń kọrin sí Jèhófà.+ (Ọba Dáfídì ṣe àwọn ohun ìkọrin yìí láti máa fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, nígbà tí Dáfídì bá ń yin Ọlọ́run pẹ̀lú wọn,* “nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”) Àwọn àlùfáà ń fun kàkàkí kíkankíkan+ níwájú wọn, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà ní ìdúró.
-