18 Gbogbo ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Áárónì ni yóò jẹ+ ẹ́. Yóò jẹ́ ìpín wọn títí lọ látinú àwọn ọrẹ àfinásun+ sí Jèhófà, jálẹ̀ àwọn ìran wọn. Gbogbo ohun tó bá fara kàn wọ́n* yóò di mímọ́.’”
13 Kó wá pa ọmọ àgbò náà níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran+ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹran ẹbọ sísun, ní ibi mímọ́, torí pé àlùfáà ló ni+ ẹbọ ẹ̀bi, bíi ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ohun mímọ́ jù lọ ni.+