-
Ẹ́kísódù 19:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Bí ìró ìwo náà ṣe túbọ̀ ń dún kíkankíkan, Mósè sọ̀rọ̀, Ọlọ́run tòótọ́ sì dá a lóhùn.*
-
-
Diutarónómì 4:10-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ní ọjọ́ tí o dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Hórébù, Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn èèyàn náà jọ sọ́dọ̀ mi kí n lè mú kí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi,+ kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi+ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi wà láàyè lórí ilẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ àwọn ọmọ wọn.’+
11 “Ẹ wá sún mọ́ tòsí òkè náà, ẹ sì dúró sí ìsàlẹ̀ rẹ̀, òkè náà sì ń yọ iná títí dé ọ̀run;* òkùnkùn ṣú, ìkùukùu* yọ, ojú ọjọ́ sì ṣú dùdù.+ 12 Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá yín sọ̀rọ̀ látinú iná náà.+ Ẹ̀ ń gbọ́ tí ẹnì kan ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò rí ẹnì kankan,+ ohùn nìkan lẹ̀ ń gbọ́.+ 13 Ó sì kéde májẹ̀mú rẹ̀ fún yín,+ èyí tó pa láṣẹ fún yín pé kí ẹ máa pa mọ́, ìyẹn Òfin Mẹ́wàá.*+ Lẹ́yìn náà, ó kọ ọ́ sórí wàláà òkúta méjì.+
-