ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 18:6-8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Nígbà tí Dáfídì àti àwọn tó kù ń pa dà láti ibi tí wọ́n ti lọ pa àwọn Filísínì, àwọn obìnrin jáde látinú gbogbo ìlú Ísírẹ́lì láti fi orin+ àti ijó pàdé Ọba Sọ́ọ̀lù, wọ́n ń lu ìlù tanboríìnì,+ wọ́n sì ń ta gòjé tìdùnnútìdùnnú. 7 Àwọn obìnrin tó ń ṣe ayẹyẹ náà ń kọrin pé:

      “Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,

      Àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá.”+

      8 Inú bí Sọ́ọ̀lù gan-an,+ orin yìí sì bà á lọ́kàn jẹ́, ó sọ pé: “Wọ́n fún Dáfídì ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún, àmọ́ wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ipò ọba nìkan ló kù kí wọ́n fún un!”+

  • 1 Sámúẹ́lì 29:4, 5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Àmọ́ inú bí àwọn ìjòyè Filísínì sí Ákíṣì gan-an, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ní kí ọkùnrin náà pa dà.+ Kó pa dà sí àyè tí o yàn án sí. Má ṣe jẹ́ kó bá wa lọ sójú ogun, kó má bàa yíjú pa dà sí wa lójú ogun.+ Ọ̀nà wo ni ì bá tún gbà wá ojú rere olúwa rẹ̀ ju pé kó fi orí àwọn èèyàn wa lé e lọ́wọ́? 5 Ṣé kì í ṣe Dáfídì tí wọ́n kọrin fún, tí wọ́n sì ń jó fún nìyí, tí wọ́n ń sọ pé:

      ‘Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,

      Àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá’?”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́