37Bẹ́sálẹ́lì+ wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe Àpótí.+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjì ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+
2 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ pé kó má kàn wá sínú ibi mímọ́+ tó wà lẹ́yìn aṣọ ìdábùú+ nígbàkigbà, níwájú ìbòrí Àpótí, kó má bàa kú,+ torí màá fara hàn nínú ìkùukùu*+ lórí ìbòrí+ náà.