-
Sáàmù 18:31-42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Ta ni Ọlọ́run bí kò ṣe Jèhófà?+
Ta sì ni àpáta bí kò ṣe Ọlọ́run wa?+
33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bíi ti àgbọ̀nrín,
Ó sì mú mi dúró ní àwọn ibi gíga.+
34 Ó ń kọ́ ọwọ́ mi ní ogun,
Apá mi sì lè tẹ ọrun tí a fi bàbà ṣe.
35 O fún mi ní apata rẹ láti gbà mí là,+
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń tì mí lẹ́yìn,*
Ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì sọ mí di ẹni ńlá.+
37 Màá lépa àwọn ọ̀tá mi, màá sì bá wọn;
Mi ò ní pa dà títí wọ́n á fi pa rẹ́.
38 Màá fọ́ wọn túútúú, kí wọ́n má lè gbérí mọ́;+
Wọ́n á ṣubú sábẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39 Wàá fún mi lókun láti jagun,
Wàá sì mú kí àwọn ọ̀tá mi ṣubú sábẹ́ mi.+
41 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ẹni tó máa gbà wọ́n;
Kódà, wọ́n ké pe Jèhófà, àmọ́ kò dá wọn lóhùn.
42 Màá gún wọn kúnná bí eruku inú ẹ̀fúùfù,
Màá sì dà wọ́n nù bí ẹrẹ̀ ojú ọ̀nà.
-