ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 9:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Èyí ni ìròyìn nípa àwọn tí Ọba Sólómọ́nì ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun+ láti kọ́ ilé Jèhófà,+ ilé* tirẹ̀, Òkìtì,*+ ògiri Jerúsálẹ́mù, Hásórì,+ Mẹ́gídò+ àti Gésérì.+

  • 2 Kíróníkà 35:20-25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan yìí, tí Jòsáyà ti múra tẹ́ńpìlì* náà sílẹ̀, Nékò+ ọba Íjíbítì wá jà ní Kákémíṣì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Yúfírétì. Ni Jòsáyà bá jáde lọ dojú kọ ọ́.+ 21 Torí náà, ó rán àwọn òjíṣẹ́ sí Jòsáyà, ó ní: “Kí ló kàn ọ́ nínú ọ̀ràn yìí, ìwọ ọba Júdà? Ìwọ kọ́ ni mo wá bá jà lónìí, ilé mìíràn ni mo wá bá, Ọlọ́run sì sọ fún mi pé kí n ṣe kíá. Torí náà, fún àǹfààní ara rẹ, má dojú kọ Ọlọ́run, ẹni tó wà pẹ̀lú mi, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa pa ọ́ run.” 22 Síbẹ̀, Jòsáyà kò pa dà lẹ́yìn rẹ̀, ńṣe ló para dà+ láti lọ bá a jà, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ Nékò, èyí tó wá láti ẹnu Ọlọ́run. Torí náà, ó wá jà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò.+

      23 Àwọn tafàtafà ta Ọba Jòsáyà lọ́fà, ọba sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbé mi kúrò níbí, torí mo ti fara gbọgbẹ́ gan-an.” 24 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbé e kúrò nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, wọ́n sì fi kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ kejì gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe kú nìyẹn, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba ńlá rẹ̀,+ gbogbo Júdà àti Jerúsálẹ́mù sì ṣọ̀fọ̀ Jòsáyà. 25 Jeremáyà+ sun rárà fún Jòsáyà, gbogbo akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ sì ń sọ nípa Jòsáyà nínú orin arò* wọn títí di òní yìí; wọ́n pinnu pé kí wọ́n máa kọ àwọn orin náà ní Ísírẹ́lì, wọ́n sì wà lákọsílẹ̀ nínú àwọn orin arò.

  • Sekaráyà 12:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n á pohùn réré ẹkún gan-an ní Jerúsálẹ́mù, bí ẹkún tí wọ́n sun ní Hadadirímónì ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́