-
Ẹ́kísódù 12:3-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Lọ́jọ́ kẹwàá oṣù yìí, kí kálukú wọn mú àgùntàn kan+ fún ilé bàbá wọn, àgùntàn kan fún ilé kan. 4 Àmọ́ tí àgùntàn kan bá ti pọ̀ jù fún agbo ilé náà, kí àwọn àti aládùúgbò wọn* tó múlé tì wọ́n jọ pín in nínú ilé wọn, kí wọ́n pín in sí iye èèyàn* tí wọ́n jẹ́. Kí ẹ ṣírò iye ẹran àgùntàn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa jẹ. 5 Kí ara àgùntàn yín dá ṣáṣá,+ kó jẹ́ akọ, ọlọ́dún kan. Ẹ lè mú lára àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́. 6 Kí ẹ máa tọ́jú rẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí,+ kí gbogbo àpéjọ* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pa á ní ìrọ̀lẹ́.*+ 7 Kí wọ́n mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì wọ́n ọn sára òpó méjèèjì ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ọ̀nà àwọn ilé tí wọ́n ti jẹ ẹ́.+
8 “‘Kí wọ́n jẹ ẹran náà lálẹ́ yìí.+ Kí wọ́n yan án lórí iná, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú+ àti ewébẹ̀ kíkorò.+ 9 Ẹ má jẹ ẹ́ ní tútù tàbí ní bíbọ̀, ẹ má fi omi sè é, àmọ́ ẹ yan án lórí iná, ẹ yan orí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àwọn nǹkan inú rẹ̀. 10 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan lára rẹ̀ kù di àárọ̀, àmọ́ tí ìkankan lára rẹ̀ bá ṣẹ́ kù di àárọ̀, kí ẹ fi iná sun ún.+ 11 Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí, ẹ di àmùrè,* ẹ wọ bàtà, kí ẹ mú ọ̀pá yín dání; kí ẹ sì yára jẹ ẹ́. Ìrékọjá Jèhófà ni.
-