ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 18:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ní ọdún kẹta Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Hẹsikáyà+ ọmọ Áhásì+ ọba Júdà di ọba.

  • 2 Àwọn Ọba 18:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì; kò sí ẹnì kankan tó dà bíi rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọba Júdà tó wà ṣáájú rẹ̀ àti àwọn tí wọ́n jẹ lẹ́yìn rẹ̀.

  • 1 Kíróníkà 5:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bá wọn jà, tó fi jẹ́ pé a fi àwọn ọmọ Hágárì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú wọn lé wọn lọ́wọ́, torí pé wọ́n ké pe Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ nínú ogun náà, ó sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.+

  • 2 Kíróníkà 16:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ṣebí àwọn ará Etiópíà àti àwọn ará Líbíà ní àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ rẹpẹtẹ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú àwọn agẹṣin? Àmọ́ torí pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+

  • Sáàmù 22:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Ìwọ ni wọ́n ké pè, o sì gbà wọ́n;

      Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọ, o ò sì já wọn kulẹ̀.*+

  • Sáàmù 37:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́;*+

      Gbẹ́kẹ̀ lé e, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.+

  • Náhúmù 1:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Jèhófà jẹ́ ẹni rere,+ odi agbára ní ọjọ́ wàhálà.+

      Ó sì mọ* àwọn tó ń wá ibi ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́