-
1 Kíróníkà 29:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Wọ́n ń rú àwọn ẹbọ sí Jèhófà, wọ́n sì ń rú àwọn ẹbọ sísun+ sí Jèhófà ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ ọmọ màlúù, ẹgbẹ̀rún (1,000) àgbò, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn; àwọn ẹbọ tí wọ́n rú nítorí gbogbo Ísírẹ́lì pọ̀ gan-an.+ 22 Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu níwájú Jèhófà ní ọjọ́ yẹn tìdùnnútìdùnnú,+ wọ́n fi Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì jẹ ọba lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì fòróró yàn án níwájú Jèhófà láti jẹ́ aṣáájú,+ bákan náà wọ́n yan Sádókù láti jẹ́ àlùfáà.+
-