-
Nehemáyà 7:66-69Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
66 Iye gbogbo ìjọ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́ta (42,360),+ 67 yàtọ̀ sí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin wọn,+ tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́tàdínlógójì (7,337); wọ́n tún ní àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tí wọ́n jẹ́ igba ó lé márùnlélógójì (245). 68 Ẹṣin wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́rìndínlógójì (736), ìbaaka wọn jẹ́ igba ó lé márùnlélógójì (245), 69 ràkúnmí wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé márùndínlógójì (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ogún (6,720).
-