33 Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn fàdákà àti wúrà àti àwọn nǹkan èlò nínú ilé Ọlọ́run wa,+ a sì kó wọn fún Mérémótì+ ọmọ àlùfáà Úríjà, Élíásárì ọmọ Fíníhásì sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àwọn ọmọ Léfì tó wà pẹ̀lú wọn ni Jósábádì+ ọmọ Jéṣúà àti Noadáyà ọmọ Bínúì.+
7 Jéṣúà, Bánì, Ṣerebáyà,+ Jámínì, Ákúbù, Ṣábétáì, Hodáyà, Maaseáyà, Kélítà, Asaráyà, Jósábádì,+ Hánánì àti Pẹláyà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, ń ṣàlàyé Òfin náà fún àwọn èèyàn náà,+ orí ìdúró sì ni àwọn èèyàn náà wà.