ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 28:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 “Ìwọ Sólómọ́nì ọmọ mi, mọ Ọlọ́run bàbá rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn*+ àti inú dídùn* sìn ín, nítorí gbogbo ọkàn ni Jèhófà ń wá,+ ó sì ń fi òye mọ gbogbo èrò àti ìfẹ́ ọkàn.+ Tí o bá wá a, á jẹ́ kí o rí òun,+ àmọ́ tí o bá fi í sílẹ̀, á kọ̀ ẹ́ sílẹ̀ títí láé.+

  • Sáàmù 62:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Bákan náà, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́ tìrẹ, Jèhófà,+

      Nítorí o máa ń san kálukú lẹ́san iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+

  • Òwe 24:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Tí o bá sọ pé: “Ṣebí a ò mọ̀ nípa rẹ̀,”

      Ṣé Ẹni tó ń ṣàyẹ̀wò ọkàn* kò mọ̀ ni?+

      Bẹ́ẹ̀ ni, Ẹni tó ń wò ọ́* máa mọ̀

      Yóò sì san ẹnì kọ̀ọ̀kan lẹ́san gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.+

  • Jeremáyà 32:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ìpinnu rẹ* ga, àwọn iṣẹ́ rẹ sì tóbi,+ ìwọ tí ojú rẹ ń wo gbogbo ọ̀nà àwọn èèyàn,+ láti san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe.+

  • Ìsíkíẹ́lì 33:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 “Àmọ́ ẹ ti sọ pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́.’+ Èmi yóò fi ìwà kálukú dá a lẹ́jọ́, ìwọ ilé Ísírẹ́lì.”

  • Róòmù 2:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Yóò san kálukú lẹ́san gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀:+

  • 2 Kọ́ríńtì 5:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Nítorí gbogbo wa ló máa fara hàn* níwájú ìjókòó ìdájọ́ Kristi, kí kálukú lè gba èrè àwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà nínú ara, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.*+

  • Gálátíà 6:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ: Ọlọ́run kò ṣeé tàn.* Nítorí ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká;+

  • 1 Pétérù 1:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Tí ẹ bá sì ń ké pe Baba tó ń fi iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣèdájọ́ láìṣe ojúsàájú,+ ẹ máa fi ìbẹ̀rù hùwà+ ní àkókò tí ẹ fi jẹ́ olùgbé fún ìgbà díẹ̀.*

  • Ìfihàn 22:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “‘Wò ó! Mò ń bọ̀ kíákíá, èrè tí mo sì ń fúnni wà pẹ̀lú mi, láti san ẹ̀san fún kálukú bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bá ṣe rí.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́