-
1 Sámúẹ́lì 2:22-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Élì ti darúgbó gan-an, àmọ́ ó ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe+ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti bí wọ́n ṣe ń bá àwọn obìnrin tó ń sìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé sùn.+ 23 Ó sì máa ń sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí? Ohun tí mò ń gbọ́ nípa yín látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn kò dáa. 24 Kò dáa bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ìròyìn tí mò ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà kò dáa. 25 Bí èèyàn bá ṣẹ èèyàn bíi tirẹ̀, ẹnì kan lè bá a bẹ Jèhófà;* àmọ́ tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni èèyàn ṣẹ̀,+ ta ló máa gbàdúrà fún un?” Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sí bàbá wọn, nítorí pé Jèhófà ti pinnu láti pa wọ́n.+
-
-
1 Sámúẹ́lì 8:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Nígbà tí Sámúẹ́lì darúgbó, ó yan àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti máa ṣe onídàájọ́ Ísírẹ́lì. 2 Orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí ni Jóẹ́lì, orúkọ èkejì sì ni Ábíjà;+ wọ́n jẹ́ onídàájọ́ ní Bíá-ṣébà. 3 Àmọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀; ọkàn wọn ń fà sí jíjẹ èrè tí kò tọ́,+ wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+ wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.+
-