ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Òwe 6:6-11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ;+

      Kíyè sí àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì gbọ́n.

       7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, aláṣẹ tàbí alákòóso,

       8 Ó ń ṣètò oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn,+

      Ó sì ń kó oúnjẹ rẹ̀ jọ nígbà ìkórè.

       9 Ìgbà wo ni ìwọ ọ̀lẹ máa dùbúlẹ̀ dà?

      Ìgbà wo lo máa dìde lójú oorun rẹ?

      10 Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀,

      Kíkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,+

      11 Ipò òṣì rẹ yóò sì dé bí olè,

      Àti àìní rẹ bí ọkùnrin tó dìhámọ́ra.+

  • Òwe 13:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ọ̀lẹ ń fẹ́, síbẹ̀ kò* ní nǹkan kan,+

      Àmọ́ ẹni* tó ń ṣiṣẹ́ kára yóò ní ànító.*+

  • Òwe 19:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú abọ́ oúnjẹ,

      Àmọ́ kò wulẹ̀ janpata láti gbé e pa dà sí ẹnu.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́