ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 15:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Kí o lawọ́ sí i dáadáa,+ kí o* má sì ráhùn tí o bá ń fún un, torí èyí á mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àtàwọn ohun tí o bá dáwọ́ lé.+ 11 Torí pé ìgbà gbogbo ni àwọn òtòṣì á máa wà ní ilẹ̀ rẹ.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé, ‘Kí o lawọ́ dáadáa sí arákùnrin rẹ tí ìyà ń jẹ tó sì tòṣì ní ilẹ̀ rẹ.’+

  • Òwe 19:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+

      Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+

  • Lúùkù 14:13, 14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Àmọ́ tí o bá se àsè, àwọn aláìní, arọ, àwọn tí kò lè rìn dáadáa àti afọ́jú ni kí o pè;+ 14 o sì máa láyọ̀, torí wọn ò ní ohunkóhun láti fi san án pa dà fún ọ. A máa san án pa dà fún ọ nígbà àjíǹde+ àwọn olódodo.”

  • Hébérù 6:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Torí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀ + bí ẹ ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí ẹ sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́