ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 25:9-11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba+ pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù;+ ó tún sun ilé gbogbo àwọn ẹni ńlá.+ 10 Gbogbo ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká ni gbogbo àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ wó lulẹ̀.+ 11 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn tó wà ní ìlú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì àti àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó kù.+

  • 2 Kíróníkà 36:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn+ nínú ibi mímọ́ wọn;+ kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin,* arúgbó tàbí aláàárẹ̀.+ Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́.+

  • 2 Kíróníkà 36:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ó sun ilé Ọlọ́run tòótọ́ kanlẹ̀,+ ó wó ògiri Jerúsálẹ́mù lulẹ̀,+ ó sun gbogbo àwọn ilé gogoro tó láàbò, ó sì ba gbogbo ohun tó ṣeyebíye jẹ́.+

  • Nehemáyà 1:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Wọ́n sọ pé: “Àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìpínlẹ̀* Júdà, tí wọ́n yè bọ́ lóko ẹrú wà nínú ìṣòro ńlá, ìtìjú sì bá wọn.+ Àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀,+ wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀.”+

  • Jeremáyà 52:13-15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù; ó sì tún sun gbogbo ilé ńlá. 14 Gbogbo ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká ni gbogbo àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ wó lulẹ̀.+

      15 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ sì kó àwọn kan lára àwọn aláìní nínú àwọn èèyàn náà àti àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìlú náà lọ sí ìgbèkùn. Ó tún kó àwọn tó sá lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì àti ìyókù àwọn àgbà oníṣẹ́ ọnà lọ sí ìgbèkùn.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́