ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 23:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Ìkéde nípa Tírè:+

      Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì!+

      Torí a ti run èbúté; kò ṣeé wọ̀.

      A ti ṣi í payá fún wọn láti ilẹ̀ Kítímù.+

  • Àìsáyà 23:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Kí ojú tì ọ́, ìwọ Sídónì, ìwọ ibi ààbò òkun,

      Torí òkun ti sọ pé:

      “Mi ò ní ìrora ìrọbí, mi ò sì tíì bímọ,

      Bẹ́ẹ̀ ni mi ò tọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin* dàgbà.”+

  • Jeremáyà 25:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Torí náà, mo gba ife náà lọ́wọ́ Jèhófà, mo sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà rán mi sí mu ún:+

  • Jeremáyà 25:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 gbogbo ọba Tírè, gbogbo ọba Sídónì+ àti àwọn ọba erékùṣù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkun,

  • Jeremáyà 27:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 “Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí, ‘Ṣe àwọn ọ̀já àti àwọn ọ̀pá àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wọ́n sí ọrùn rẹ. 3 Lẹ́yìn náà, fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọba Édómù,+ ọba Móábù,+ ọba àwọn ọmọ Ámónì,+ ọba Tírè+ àti ọba Sídónì+ nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ tó wá sí Jerúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà ọba Júdà.

  • Ìsíkíẹ́lì 28:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 “Ọmọ èèyàn, yíjú rẹ sọ́dọ̀ Sídónì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀.

  • Jóẹ́lì 3:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Kí ló dé tí ẹ fi ṣe báyìí sí mi,

      Tírè, Sídónì àti gbogbo ilẹ̀ Filísíà?

      Ṣé mo ṣẹ̀ yín ni tí ẹ fi ń gbẹ̀san?

      Tó bá jẹ́ ẹ̀san lẹ̀ ń gbà,

      Ṣe ni màá yára dá a pa dà sórí yín láìjáfara.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́