ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 2:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Àwọn àlùfáà kò béèrè pé, ‘Ibo ni Jèhófà wà?’+

      Àwọn tó ń kọ́ni ní Òfin kò sì mọ̀ mí,

      Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣọ̀tẹ̀ sí mi,+

      Àwọn wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ Báálì,+

      Wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan.

  • Jeremáyà 8:10-12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Torí náà, màá fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin míì,

      Màá fi oko wọn fún àwọn tó máa gbà á;+

      Látorí ẹni kékeré títí dórí ẹni ńlá, kálukú wọn ń jẹ èrè tí kò tọ́;+

      Látorí wòlíì títí dórí àlùfáà, kálukú wọn ń lu jìbìtì.+

      11 Wọ́n sì ń wo àárẹ̀* ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi sàn láàbọ̀,* wọ́n ń sọ pé,

      “Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!”

      Nígbà tí kò sí àlàáfíà.+

      12 Ǹjẹ́ ojú tì wọ́n nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe?

      Ojú kì í tì wọ́n!

      Àní wọn ò tiẹ̀ lójútì rárá!+

      Torí náà, wọ́n á ṣubú láàárín àwọn tó ti ṣubú.

      Nígbà tí mo bá fìyà jẹ wọ́n, wọ́n á kọsẹ̀,’+ ni Jèhófà wí.

  • Jeremáyà 23:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 “Nítorí pé wòlíì àti àlùfáà ti di eléèérí.*+

      Kódà, mo ti rí ìwà búburú wọn nínú ilé mi,”+ ni Jèhófà wí.

  • Míkà 3:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí nípa àwọn wòlíì tó ń ṣi àwọn èèyàn mi lọ́nà,+

      Tí wọ́n ń kéde ‘Àlàáfíà!’+ nígbà tí wọ́n bá ń rí nǹkan jẹ,*+

      Àmọ́ tí wọ́n ń gbógun ti* ẹni tí kò fún wọn ní nǹkan kan jẹ:

  • Míkà 3:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Àwọn olórí* rẹ̀ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó dájọ́,+

      Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń gba owó kí wọ́n tó kọ́ni,+

      Àwọn wòlíì rẹ̀ ń gba owó* kí wọ́n tó woṣẹ́.+

      Síbẹ̀ wọ́n gbára lé Jèhófà,* wọ́n ń sọ pé:

      “Ṣebí Jèhófà wà pẹ̀lú wa?+

      Àjálù kankan ò lè dé bá wa.”+

  • Sefanáyà 3:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Aláfojúdi ni àwọn wòlíì rẹ̀, oníbékebèke ni wọ́n.+

      Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń sọ ohun mímọ́ di ẹlẹ́gbin;+

      Wọ́n ń rú òfin.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́