-
Nọ́ńbà 13:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Páránì, ní Kádéṣì.+ Wọ́n jábọ̀ fún gbogbo àpéjọ náà, wọ́n sì fi àwọn èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Ohun tí wọ́n ròyìn fún Mósè ni pé: “A dé ilẹ̀ tí o rán wa lọ, wàrà àti oyin+ sì ń ṣàn níbẹ̀ lóòótọ́, àwọn èso+ ibẹ̀ nìyí.
-
-
Diutarónómì 6:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé òun máa fún ọ,+ àwọn ìlú tó tóbi tó sì dára, tí kì í ṣe ìwọ lo kọ́ ọ,+ 11 àwọn ilé tí gbogbo onírúurú ohun rere tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fún kún inú wọn, àwọn kòtò omi tí ìwọ kò gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti igi ólífì tí ìwọ kò gbìn, tí o jẹ, tí o sì yó,+
-
-
Diutarónómì 8:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Torí ilẹ̀ dáradára ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń mú ọ lọ,+ ilẹ̀ tí omi ti ń ṣàn,* tí omi ti ń sun jáde, tí omi sì ti ń tú jáde* ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ní agbègbè olókè, 8 ilẹ̀ tí àlìkámà* àti ọkà bálì kún inú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì,+ ilẹ̀ tí òróró ólífì àti oyin kún inú rẹ̀,+ 9 ilẹ̀ tí oúnjẹ ò ti ní wọ́n ọ, tó ò sì ní ṣaláìní ohunkóhun, ilẹ̀ tí irin wà nínú àwọn òkúta rẹ̀, tí wàá sì máa wa bàbà látinú àwọn òkè rẹ̀.
-