-
Jeremáyà 18:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 “Ní báyìí, jọ̀wọ́ sọ fún àwọn èèyàn Júdà àti àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, mò ń ṣètò àjálù kan fún yín, mo sì ń pète ohun kan fún yín. Torí náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe.”’”+
-
-
Jeremáyà 35:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Mo sì ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mò ń rán wọn léraléra,*+ wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà, kí kálukú yín kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀,+ kí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́! Ẹ má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, ẹ má sì sìn wọ́n. Nígbà náà, ẹ ó máa gbé ní ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.’+ Ṣùgbọ́n ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀, ẹ kò sì fetí sí mi.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 18:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “‘Torí náà, màá fi ìwà yín dá kálukú yín lẹ́jọ́,+ ilé Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ẹ yí pa dà, àní ẹ yí pa dà pátápátá kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí wọ́n má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó máa mú kí ẹ jẹ̀bi.
-