ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 9:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 ṣe ni màá ké Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+

  • Jeremáyà 7:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “‘Àmọ́, ní báyìí ẹ lọ sí àyè mi ní Ṣílò,+ níbi tí mo mú kí orúkọ mi wà ní ìbẹ̀rẹ̀,+ kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì.+

  • Jeremáyà 7:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Bí mo ti ṣe sí Ṣílò, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe sí ilé tí a fi orúkọ mi pè,+ èyí tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé+ àti sí ibi tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.+

  • Dáníẹ́lì 9:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ọlọ́run mi, tẹ́tí sílẹ̀, kí o sì gbọ́! La ojú rẹ, kí o sì rí ìyà tó ń jẹ wá àti bí ìlú tí a fi orúkọ rẹ pè ṣe di ahoro; kì í ṣe torí àwọn ìṣe òdodo wa la ṣe ń bẹ̀ ọ́, torí àánú rẹ tó pọ̀ ni.+

  • Hósíà 12:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Jèhófà máa pe Júdà lẹ́jọ́;+

      Ó máa pe Jékọ́bù wá jíhìn nítorí àwọn ọ̀nà rẹ̀,

      Ó sì máa san án lẹ́san àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+

  • Míkà 6:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Ẹ gbọ́ ẹjọ́ Jèhófà, ẹ̀yin òkè

      Àti ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayé tó fìdí múlẹ̀,+

      Torí Jèhófà fẹ́ pe àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́jọ́;

      Yóò sì bá Ísírẹ́lì ro ẹjọ́ pé:+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́