-
2 Àwọn Ọba 24:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí ìlú náà nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dó tì í.
-
-
2 Kíróníkà 36:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nebukadinésárì kó lára àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà lọ sí Bábílónì, ó sì kó wọn sínú ààfin rẹ̀ ní Bábílónì.+
-
-
Jeremáyà 28:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Ní ọdún yẹn kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà+ ọba Júdà, ní ọdún kẹrin, ní oṣù karùn-ún, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì láti Gíbíónì+ sọ fún mi ní ilé Jèhófà lójú àwọn àlùfáà àti lójú gbogbo àwọn èèyàn náà pé: 2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Màá ṣẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.+ 3 Kí ọdún* méjì tó pé, gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó láti ibí yìí lọ sí Bábílónì ni màá kó pa dà wá sí ibí yìí.’”+
-
-
Dáníẹ́lì 1:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
1 Ní ọdún kẹta àkóso Jèhóákímù+ ọba Júdà, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì pàgọ́ tì í.+ 2 Nígbà tó yá, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò kan ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́, ó sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì*+ sí ilé* ọlọ́run rẹ̀. Ó kó àwọn ohun èlò náà sínú ilé ìṣúra ọlọ́run rẹ̀.+
-